orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kọ̀ Láti Lọ Sí Kénánì

1. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sunkún ní òru ọjọ́ náà.

2. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sì kùn sí Mósè àti Árónì, gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì wí fún wọn pé; “Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Éjíbítì. Tàbí kí a kúkú kú sínú ihà yìí.

3. Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá?, Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Éjíbítì?”

4. Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Éjíbítì.”

5. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì dojú bolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Ísírẹ́lì.

6. Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya.

7. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì pé, “Ìlẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.

8. Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.

9. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”

10. Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fara hàn ní Àgọ́ Ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Mósè Bẹ̀bẹ̀ Fún Àwọn Ènìyàn

11. Olúwa sọ fún Mósè pé: “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrin wọn?

12. Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”

13. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára Írẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrin wọn.

14. Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùukùu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùukùu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru.

15. Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀ èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé.

16. ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú ihà yìí.’

17. “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣọ pé:

18. ‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró sinsin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jìn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’

19. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jìn wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Éjíbítì di ìsin yìí.”

20. Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dárí jìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ;

21. Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láàyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa.

22. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí òg mi àti wọn iṣẹ́ àmì ìyanu tí mo ṣe ní ilẹ̀ Éjíbítì àti nínú ihà ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí,

23. Ọ̀kan nínú wọn kò níi rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà.

24. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kélẹ́bù ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mi ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.

25. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì ń gbé ní àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojú kọ ihà lọ́nà Òkun Pupa.”

26. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

27. “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sími? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí mi.

28. Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.

29. Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.

30. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra láti fi ṣe ilẹ̀ yín, àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jósúà ọmọ Núnì.

31. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀.

32. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní ihà yìí.

33. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú ihà fun ogójì ọdún (40) wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní ihà.

34. Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.

35. Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kóra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú ihà yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

36. Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú àwọn ènìyàn kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

37. Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-àrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa.

38. Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ló yè é.

39. Nígbà tí Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì sunkún gidigdidi.

40. Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ síbi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”

41. Mósè sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!

42. Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrin yín. Ki á má baà lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀ta yín.

43. Nítorí pé àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará Kénánì yóò kojú yín níbẹ̀. Nítorí pé Ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”

44. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láì jẹ́ pé àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa tàbí Mósè kúrò nínú ibùdó.

45. Àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Hómà.