orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìkànìyàn Ẹlẹ́ẹ̀kejì

1. Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-àrùn Olúwa sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà pé

2. “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Ísírẹ́lì.”

3. Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Móábù pẹ̀lú Jọ́dánì tí ó kọjá Jẹ́ríkò, Mósè àti Élíásárì àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,

4. “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.”Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde láti Éjíbítì wá:

5. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì,láti ẹni ti ìdílé Hánókù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hánókù ti jáde wá;Láti ìdílé Pálù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pálù ti jáde wá;

6. ti Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì;ti Kárímì, ìdílé àwọn ọmọ Kárímì.

7. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).

8. Àwọn ọmọkùnrin Pálù ni Élíábù,

9. àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù. Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.

10. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kórà, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tàlérúgba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.

11. Àwọn ọmọ Kórà, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12. Àwọn ọmọ ìrán Símónì bí ìdílé wọn:ti Némúélì, ìdílé Némúélì;ti Jámínì, ìdílé Jámínì;ti Jákínì, ìdílé Jákínì;

13. ti Ṣérà, ìdílé Ṣérà;tí Ṣọ́ọ̀lù, ìdílé Ṣọ́ọ̀lù.

14. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Símónì, ẹgbàámọ́kànlá ó lé igba. (22,200) ọkùnrin.

15. Àwọn ọmọ Gádì bí ìdílé wọn:ti Ṣéfónì, ìdílé Ṣéfónì;ti Hágígì, ìdílé Hágígì;ti Ṣúnì, ìdílé Ṣúnì;

16. ti Ósínì, ìdílé Ósíní;ti Érì, ìdílé Érì;

17. ti Árédì, ìdílé Árédì;ti Árólì, ìdílé Árólì.

18. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

19. Àwọn ọmọ Júdà ni Érì àti Ónánì, ṣùgbọ́n Érì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénánì.

20. Àti àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ṣélà, ìdílé Ṣélà;ti Pérésì, ìdílé Pérésì;ti Sérà, ìdílé Ṣérà.

21. Àwọn ọmọ Pérésì:ti Hésírónì, ìdílé Hésírónì;ti Hámúlù, ìdílé Hámúlù.

22. Wọ̀nyí ni ìdílé Júdà; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).

23. Àwọn ọmọ Isákárì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Tólà, ìdílé Tólà;ti Púfà, ìdílé Púfà;

24. ti Jáṣúbù, ìdílé Jáṣúbù;ti Ṣímírónì, ìdílé Ṣímírónì.

25. Wọ̀nyí ni ìdílé Isákárì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó léọ̀ọ́dúnrún (64,300).

26. Àwọn ọmọ Ṣebúlúnì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Sẹ́rẹ́dì, ìdílé Ṣẹ́rẹ́dì;ti Élónì, ìdílé Élónì;ti Jálélì, ìdílé Jálélì.

27. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebúlúnì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

28. Àwọn ọmọ Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Mánásè àti Éfúráímù:

29. Àwọn ọmọ Mánásè:ti Mákírì, ìdílé Mákírì (Mákírì sì bí Gílíádì);ti Gílíádì, ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì.

30. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì:ti Íésérì, ìdílé Íésérì;ti Hélékì, ìdílé Hélékì

31. àti ti Ásíríẹ́lì, ìdílé Ásíríẹ́lì;àti ti Ṣékémù, ìdílé Ṣékémù;

32. àti Ṣemídà, ìdílé àwọ ọmọ Ṣemídà;àti ti Heférì, ìdílé àwọn ọmọ Héférì.

33. (Selofehádì ọmọ Héférì kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin Selofehádì ni Málà, Nóà, àti Hógílà, Mílíkà àti Táṣà).

34. Wọ̀nyí ni ìdílé Mánásè tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

35. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:láti ọ̀dọ̀ Ṣútẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Ṣútẹ́là;ti Békérì, ìdílé àwọn ọmọ Békérì;ti Táhánì, ìdílé àwọn ọmọ Táhánì.

36. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣútélà:ti Éránì, ìdílé àwọn ọmo Éránì;

37. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfurémù, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàámẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38. Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nì yí:tí Bẹ́là, ìdílé àwọn ọmọ Bẹ́là;ti Ásíbérì, ìdílé àwọn ọmọ Ásíbérì;ti Áhírámù, ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù;

39. ti Ṣúfámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúfámù;ti Húfámù, ìdílé àwọn ọmọ Húfámù.

40. Àwọn ọmọ Bẹ́là ní pasẹ̀ Árídì àti Náámánì nì yí:ti Árádì, ìdílé àwọn ọmọ Árádì;ti Náámánì, ìdílé àwọn ọmọ Náámánì.

41. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ṣúhámù, ìdílé àwọn ọmọ ṢúhámùWọ̀nyí ni ìdílé Dánì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

43. Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó lé irínwó (64,400).

44. Ti àwọn ọmọ Ásérì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ímínà, ìdílé àwọn ọmọ Ímínà;ti Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì;ti Béríà, ìdílé àwọn ọmọ Béríà;

45. Ti àwọn ọmọ Béríà:ti Hébérì, ìdílé àwọn ọmọ Hébérì;ti Mákíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Mákíẹ́lì.

46. (Orúkọ ọmọ Áṣérì obìnrin nì jẹ́ Ṣérà.)

47. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbéje (53,400).

48. Ti àwọn ọmọ Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Jásélì, ìdílé àwọn ọmọ Jásélì:ti Gúnì, ìdílé àwọn ọmọ Gúnì;

49. ti Jésérì, ìdílé àwọn ọmọ Jéṣérì;ti Ṣílémù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣilemù.

50. Wọ̀nyí ni ìdílé ti Náfítalì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbéje (45,400).

51. Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (601,730).

52. Olúwa sọ fún Mósè pé,

53. “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn

54. Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.

55. Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni ín.

56. Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrin ńlá àti kékeré.”

57. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Gáṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì;ti Kóhátì, ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì;ti Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì.

58. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì;ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,ìdílé àwọn ọmọ Hébírónì,ìdílé àwọn ọmọ Málì,ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,ìdílé àwọn ọmọ Kórà.(Kóhátì ni baba Ámírámù,

59. Orúkọ aya Ámírámù sì ń jẹ́ Jókébédì, ọmọbìnrin Léfì, tí ìyá rẹ̀ bí fún Léfì ní Éjíbítì. Òun sì bí Árónì, Mósè, àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámírámù.

60. Árónì ni baba Nádábù àti Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.

61. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

62. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

63. Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.

64. Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mósè àti Árónì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ihà Sínáì.

65. Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kíkú ni wọn yóò kú sí ihà, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú à fi Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì, àti Jóṣúà ọmọ Núnì.