orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ọmọ Kóhátì

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

2. “Ka iye àwọn ọmọ Kóhátì láàrin àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

3. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.

4. “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.

5. Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.

6. Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

7. Lórí tabilì ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, wọn ó sì kó àwọn àwo, páànù, àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àkàrà tó sì máa ń wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.

8. Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

9. “Kí wọn kí ó fi aṣọ aláwọ̀ búlù bọ ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti àwo ìkó ẹ̀mu sí, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

10. Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.

11. “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

12. “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

13. “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.

14. Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò. Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

15. “Lẹ́yìn tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀ṣíwájú, kí àwọn ọmọ Kóhátì bọ́ ṣíwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kóhátì ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú Àgọ́ Ìpàdé.

16. “Iṣẹ́ Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àmójútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́.”

17. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

18. “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kóhátì kúrò lára àwọn ọmọ Léfì:

19. Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má baà kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálukú àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.

20. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

Àwọn Ọmọ Gáṣónì

21. Olúwa sọ fún Mósè pé:

22. “Tún ka iye àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

23. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

24. “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù:

25. Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti Àgọ́, ti Àgọ́ Ìpàdé àti ìborí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé,

26. Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà, okùn àti àwọn ohun èlò mìíràn tí à ń lò fún gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àwọn ọmọ Gáṣónì ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

27. Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gáṣónì yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.

28. Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gáṣónì ni Àgọ́ Ìpàdé Ítamárì, ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.

Àwọn Ọmọ Mérárì

29. “Ka iye àwọn ọmọ Mérárì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

30. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

31. Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú Àgọ́ Ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀,

32. Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un;

33. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Mérárì, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé lábẹ́ àkóso Ítamárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà.”

Àbájáde Kíka Àwọn Ọmọ Léfì

34. Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kóhátì nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

35. Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

36. Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín àádọ́ta (2,750).

37. Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kóhátì tó ń ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé; tí Mósè àti Árónì kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

38. Wọ́n ka àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ìdílé àti ile baba wọn.

39. Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

40. Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n (2,630).

41. Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gásónì, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé. Mósè àti Árónì se bí àṣẹ Olúwa.

42. Wọ́n ka àwọn ọmọ Mérárì nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

43. Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

44. Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200).

45. Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Mérárì. Mósè àti Árónì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.

46. Báyìí ni Mósè, Árónì àti olórí ìjọ ènìyàn ka gbogbo ọmọ Léfì nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

47. Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn erù inú Àgọ́ Ìpadé.

48. Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580).

49. Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mósè.Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.