orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ààlà Ti Kénánì

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kénánì, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

3. “ ‘Ìhà gúṣù yín yóò bọ́ sí ara ihà Ṣínì lẹ́bá Édómù, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà-gúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀,

4. Kọjá lọ sí Síkọ́píọ́nì, tẹ̀ṣíwájú lọ si Sínì: kó bọ́ si gúsù Kadesi-Báníyà, kí o sì dé Hasari-Ádárò, kí o sì kọjá sí Ásímónì.

5. Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun.

6. “ ‘Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn:

7. “ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì

8. Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì,

9. Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

10. “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù.

11. Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn.

12. Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun.“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

13. Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀.

14. Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn.

15. Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn.”

16. Olúwa sọ fún Mósè pé,

17. “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì.

18. Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

19. Èyí ni orúkọ wọn:Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè,láti ẹ̀yà Júdà;

20. Ṣémúélì ọmọ Ámíhúdì,láti ẹ̀yà Ṣíméónì;

21. Élídádì ọmọ Kísílónì,láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì;

22. Búkì ọmọ Jógílì,láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dánì;

23. Háníélì ọmọ Éfódù,láti ẹ̀yà Mánásè, olórí àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù,

24. Kémúélì ọmọ Ṣífílánì,olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Éfúráímù, ọmọ Jóṣẹ́fù;

25. Élísáfánì ọmọ Pánákì,olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ṣébúlunì;

26. Pátíélì ọmọ Ásánì,olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì;

27. Áhíhúdù ọmọ Ṣélómì,olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì;

28. Pédàhẹ́lì ọmọ Ámíhúdì,olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfitalì.”

29. Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénánì.