orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àṣè Ìrékọjá

1. Olúwa sọ fún Mósè nínú ihà Ṣínáì ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wí pé;

2. “Mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀.

3. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan-an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

4. Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́.

5. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ihà Ṣínáì ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

6. Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mósè àti Árónì lọ́jọ́ náà.

7. Wọ́n sọ fún Mósè pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Ísírẹ́lì yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”

8. Mósè sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pa láṣẹ nípa yín.”

9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,

10. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá mọ́.

11. Wọn yóò ṣe ti wọn ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro.

12. Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣẹ àjọ Ìrékọjá.

13. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14. “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrin yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

Ìkúùkù Lórí Àgọ́

15. Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkúùkù àwọ̀sánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkúùkù náà sì dàbí iná lórí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀.

16. Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe títí, ìkúùkù yóò bò ó lọ́sán, ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná lálẹ́.

17. Nígbàkígbà tí ìkúùkù yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkúùkù náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò pa ibùdó wọn sí.

18. Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó.

19. Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ.

20. Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; ṣíbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra.

21. Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá sì kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkigbà tí ìkúùkù bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra.

22. Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkúùkù fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn ò ní í gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra.

23. Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.