orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìkànìyàn

1. Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ihà Ṣínáì nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ó wí pé:

2. “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Ísírẹ́lì nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

3. Ìwọ àti Árónì ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.

4. Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀ láti ràn yín lọ́wọ́.

5. Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí:Láti ọ̀dọ̀ Rúbẹ́nì, Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì;

6. Láti ọ̀dọ̀ Símónì, Ṣélúmíélì ọmọ Ṣúrísáddáì;

7. Láti ọ̀dọ̀ Júdà, Násónì ọmọ Ámínádàbù;

8. Láti ọ̀dọ̀ Íssákárì, Nítaníẹ́lì ọmọ Ṣúárì;

9. Láti ọ̀dọ̀ Ṣébúlúnì, Élíábù ọmọ Hélónì;

10. Láti ọ̀dọ̀ àwọn sọmọ Jósẹ́fù:láti ọ̀dọ̀ Éfraimù, Elisámà ọmọ Ámíhúdì;Láti ọ̀dọ̀ Mánásè, Gámáélì ọmọ Pedasúrù;

11. Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì, Ábídánì ọmọ Gídíónì;

12. Láti ọ̀dọ̀ Dánì, Áhíésérì ọmọ Ámísádáì;

13. Láti ọ̀dọ̀ Áṣérì, Págíélì ọmọ Ókíránì;

14. Láti ọ̀dọ̀ Gáádì, Élíásàfu ọmọ Déúélì;

15. Láti ọ̀dọ̀ Náfítalì, Áhírà ọmọ Énánì.”

16. Àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Ísírẹ́lì.

17. Mósè àti Árónì mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí

18. wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Ísírẹ́lì jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì se àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,

19. gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paṣẹ fún Mósè. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú ihà Ṣínáì.

20. Láti ìran Rúbẹ́nì tí í se àkọ́bí Ísírẹ́lì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

21. Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹgbẹ̀ta (46,500).

22. Láti ìran Símónì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

23. Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀ya Símónì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún-ó-lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24. Láti ìran Gáádì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn.

25. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gáádì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26. Láti ìran Júdà:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

27. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-ẹgbẹ́ta (74,600).

28. Láti ìran Ísákárì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

29. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Íṣákárì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-irinwó (54,400).

30. Láti ìran Ṣébúlúnì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

31. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Ṣébúlúnì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún-ó-lé-egbéje (57,400).

32. Láti inú àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù:Láti ìran Éfúráímù:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

33. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Éfúráímù jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34. Láti ìran Mánássè:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

35. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).

36. Láti ìran Bẹ́ńjámínì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

37. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógún-ó-lé-egbéje (35,400).

38. Láti ìran Dánì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

39. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40. Láti ìran Ásérì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

41. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42. Láti ìran Náfítalì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

43. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Náfítalì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (53,400).

44. Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mósè àti Árónì kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Ísírẹ́lì, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sojú fún ìdílé rẹ̀.

45. Gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

46. Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín-àádọ́ta, (603,550).

47. A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Léfì mọ́ àwọn ìyókù.

48. Nítorí Olúwa ti sọ fún Mósè pé,

49. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Léfì, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:

50. Dípò èyí yan àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ alábojútó àgọ́. Ẹrí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójú tó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.

51. Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á

52. kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.

53. Àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; kí àwọn ọmọ Léfì sì máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”

54. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.