orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọmọbìnrin Ṣélóféhátì

1. Ọmọbìnrin Ṣélóféhátì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè tó jẹ́ ìdílé Mánásè, ọmọ Jósẹ́fù wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà.

2. Wọ́n súnmọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mósè, àti Élíásérì àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,

3. “Baba wa kú sí ihà. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

4. Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítórí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn arakùnrin baba wa.”

5. Nígbà náà Mósè mú ọ̀rọ̀ wọn wá ṣíwájú Olúwa.

6. Olúwa sì wí fún un pé,

7. “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣélófénátì ń sọ tọ̀nà. Ó gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

8. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.

9. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.

10. Tí kò bá ní arakùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀.

11. Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.’ ”

Jóṣúà Láti Rọ́pò Mósè.

12. Nígbá náà Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ sì orí òkè Ábárímù yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

13. Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Árónì arákùnrin rẹ ṣe ṣe,

14. nítórí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Ṣínì, tí gbogbo yín se àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Méríbà ní Kádésì ní ihà Sínì.)

15. Mósè sọ fún Olúwa wí pé,

16. “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí

17. Láti má a darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùsọ́”

18. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mósè pé, “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.

19. Jẹ́ kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì kí o sì fi àsẹ fún un ní ojú wọn.

20. Fún un ní ara àwọn àṣẹ rẹ kí gbogbo ìlú Ísírẹ́lì kí ó lè gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

21. Kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Úrímù níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”

22. Mósè sì se gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Jóṣúà ó sì mú kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ.

23. Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.