orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ogún Ọmọbìnrin Ṣélófíhádì

1. Àwọn olórí ìdílé Gílíádì, ọmọkùnrin Mákírì ọmọ Mánásè tí ó wá láti ara ìdílé ìrán Jósẹ́fù wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mósè àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Ísírẹ́lì.

2. Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Ṣélófíhádì arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.

3. Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Ísírẹ́lì mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbàá kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.

4. Nígbà tí ọdún Júbélì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ babańlá wọn.”

5. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìrán Jóṣẹ́fù ń ṣọ tọ̀nà.

6. Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣélófíhádì: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.

7. Kò sí ogún kan ní Ísírẹ́lì tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ babańlá wọn pamọ́.

8. Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.

9. Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”

10. Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣẹ́lófẹ́hádì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

11. Nítorí pé a gbé Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà, àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Ṣélófẹ́hádì ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.

12. Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìrán Mánásè, ọmọ Jóṣẹ́fù ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.

13. Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ tí Olúwa ti ipaṣẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.