orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Òòrùn Dúró Jẹ́.

1. Ní báyìí tí Adoni-Sédékì ọba Jérúsálẹ́mù gbọ́ pé Jóṣúà ti gba Áì, tí ó sì ti pa wọ́n pátapáta; tí ó sì ṣe sí Áì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gíbíónì ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.

2. Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gíbíónì jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Áì lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun.

3. Nítorí náà Adoni-Sédékì ọba Jérúsálẹ́mù bẹ Hóámù ọba Hébúrónì, Pírámù ọba Jámútù, Jáfíà ọba Lákíṣì àti Débírìe ọba Égílónì. Wí pe,

4. “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gíbíónì, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ́lú Jóṣúà ti àwọn ará Ísírẹ́lì.”

5. Àwọn ọba Ámórì máràrùn, ọba Jérúsálẹ́mù, Hébúrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì-kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojú kọ Gíbíónì, wọ́n sì kọ lù ú.

6. Àwọn ará Gíbíónì sì ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó ní Gílígálì pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín silẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Ámórì tí ń gbé ní orílẹ̀ èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gòkè lọ láti Gílígálì, pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

8. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojú kọ ọ́.”

9. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gílígálì, Jóṣúà sì yọ sí wọn lójijì.

10. Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gíbíónì. Ísírẹ́lì sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹti-Hórónì, ó sì pa wọ́n dé Ásékà, àti Mákédà.

11. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Ísírẹ́lì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Bẹti-Hórónì títí dé Ásékà, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọju àwọn tí àwọn ará Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.

12. Ní ọjọ̀ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Ámórì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Ísírẹ́lì:“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gíbíónì,Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Áíjálónì.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn náà sì dúró jẹ́,òṣùpá náà sì dúró,títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jáṣárì.Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.

14. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣaájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Ísírẹ́lì!

15. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì padà sí ibùdó ní Gílígálì.

A Pa Ọba Ámórì Márùn-ún

16. Ní báyìí àwọn ọba Ámórì márùn-ún ti sá lọ, wọ́n sì fara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Mákédà,

17. Nígbà tí wọ́n sọ fún Jósúà pé, a ti rí àwọn ọba máràrùn, ti ó fara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Mákédà,

18. ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.

19. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe dúró! Ẹ lépa àwọn ọ̀ta yín, ẹ kọlù wọ́n làti ẹyìn, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó dé ìlú wọn, nítorí tí Olúwa Ọlọ́run yín tí fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

20. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà àti àwọn ọmọ ogun pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ ogun àwọn ọba máràrùn run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.

21. Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Jóṣúà ní ibùdó ogun ní Mákédà ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Ísírẹ́lì.

22. Jósúà sì wí pe, “Ẹ ṣi ẹnu ihò náà, kí ẹ sì mú àwọn ọba máràrùn jáde wá fún mi.”

23. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúró nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jérúsálẹ́mù, Hẹ́búrónì, Jámútù, Lákíṣì àti Égílónì.

24. Nígbà tí wọ́n mú àwọn ọba náà tọ Jóṣúà wá, ó pe gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, ó sì sọ fún àwọn olórí ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ sún mọ́ bí, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín lé ọrùn àwọn ọba wọ̀nyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wá sí iwájú, wọ́n sì gbé ẹsẹ̀ lé ọrùn wọn.

25. Jóṣúà sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni Olúwa yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀ta yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”

26. Nígbà náà ni Jóṣúà kọlù wọ́n, ó sì pa àwọn ọba máràrùn náà, ó sì so wọ́n rọ̀ ní orí igi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ márùn-ún, wọ́n sì fi wọ́n sí orí igi títí di ìrọ̀lẹ́.

27. Nígbà tí oòrun wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ, wọ́n sì ṣọ̀ wọ́n kalẹ̀ kúró ní orí igi, wọ́n sì gbé wọn jù sí inú ihò àpáta ní ibi tí wọ́n sápamọ̀ sí. Wọ́n sì fi òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà, tí ó sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

28. Ní ọjọ́ náà Jóṣúà gba Mákédà. Ó sì fi ojú idà kọlu ìlú náà àti ọba rẹ̀, ó sì run gbogbo wọn pátapáta, kò fi ẹnìkan sílẹ̀. Ó sì ṣe sí ọba Mákédà gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.

A ṣẹ́gun àwọn ìlú ìhà gúsù.

29. Nígbà náà ní Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Mákédà lọ sí Líbínà wọ́n sì kọlù ú.

30. Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Jóṣúà fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.

31. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo ará Ísírẹ́lì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Líbínà lọ sí Lákíṣì; ó sì dótì í, ó sì kọlù ú.

32. Olúwa sì fi Lákísì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sì gbà á ní ọjọ́ kéjì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pá gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Líbínà.

33. Ní àkókò yìí, Hórámì ọba Gésérì gòkè láti ran Lákíṣì lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Jóṣúà ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.

34. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lákíṣì lọ sí Égílónì; wọ́n sì dótì í, wọ́n sì kọ lù ú.

35. Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátapáta, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lákísì.

36. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì sí láti Égílónì, lọ sí Hébúrónì, wọ́n sì kọlù ú.

37. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sìti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Égílónì, wọ́n run un pátapáta àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀.

38. Nígbà náà ni Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Débírì.

39. Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátapáta. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Débírì àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Líbínà àti ọba rẹ̀ àti sí Hébúrónì.

40. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo agbégbé náà, ìlú òkè, Négéfi, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-óòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátapáta, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti pàṣẹ.

41. Jóṣúà sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi Báníyà sí Gásà àti láti gbogbo agbègbè Góṣénì lọ sí Gíbíónì.

42. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Jósúà sẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ́ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jà fún Ísírẹ́lì.

43. Nígbà náà ni Jóṣúà padà sí ibùdó ní Gílígálì pẹ̀lú gbogbo Ísírẹ́lì.