orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpín Fún Ẹ̀yà Júdà.

1. Ìpín fún ẹ̀yà Júdà, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbégbé Édómù, títí dé ihà Síní ní òpin ìhà gúsù.

2. Ààlà wọn ní ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúsù Òkun Iyọ̀,

3. Ó sì lọ sí gúsù Sikopioni Pasi lọ títi dé Sínì àti sí iwájú ìhà gúsù Kadesi Báníyà. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hésórónì lọ sí Ádárì, ó sì tún yípo yíká lọ sí Kákà.

4. Ó tún kọjá lọ sí Ásímónì, ó sì papọ̀ mọ́ Wádì ti Éjíbítì, ó parí sí òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúsù.

5. Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jọ́dánì.Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jọ́dánì,

6. ààlà náà sì tún dé Bẹti-Hógílà, ó sì lọ sí ìhà àríwá Bẹti-Árábà. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bóhánì ti ọmọ Rúbẹ́nì.

7. Ààlà náà gòkè lọ títí dé Débírì láti Àfonífojì Ákórì, ó sì yípadà sí àríwá Gílígálì, èyí tí ó dojú kọ iwájú Ádúmímù gúsù ti Gọ́ọ́jì. Ó sì tẹ̀síwájù sí apá omi Ẹbi Ṣéméṣì, ó sì jáde sí Ẹni Rógélì.

8. Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí Àfonífojì Bẹni Hínómù ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúsù ti Jébúsì (tí í ṣe Jérúsálẹ́mù). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí Àfonífojì Hínómù ní òpín àríwá àfonífojì Réfáímù.

9. Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Néfítóà, ó sì jáde sí ìlú Okè Éífírónì, ó sì lọ sí apá ìṣàlẹ̀ Báálà, (tí í ṣe, Kiriati Jéárímù).

10. Ààlà tí ó yípo láti Báálà lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí okè Séírì, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jéárímù (tí íṣe, Késálónì), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, ó sì kọja lọ sí Tímínà.

11. Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ékírónì, ó sì yípadà lọ sí Síkerónì, ó sì yípadà lọ sí Okè Báálà, ó sì dé Jábínẹ́ẹ́lì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá.Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì. (Áríbà sì ní baba ńlá Ánákì.)

14. Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì.

15. Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Débírì (tí à ń pè ní Kiriati Séferì tẹ́lẹ̀).

16. Kélẹ́bù sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Ákísà fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati Séférì, tí ó sì gbà á ní ìgbeyàwó.”

17. Ótíniẹ́lì ọmọ Kénásì, arákùnrin Kélẹ́bù, sì gbà á, báyìí ni Kélẹ́bù sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákísà fún un ní ìyàwó.

18. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Ákísà lọ sí ọ̀dọ̀ Ótíniẹ̀lì, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Ákísà sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kélẹ́bù sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

19. Ó sì dáhùn pé, “Ṣe ojúrere àtàtà fún mi. Níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Negefi fun mi ní ìsun omi pẹ̀lú.” Báyìí ni Kélẹ́bù fún un ní ìsun omi ti òkè àti ti ìṣàlẹ̀.

20. Èyí ni ilẹ̀ ini ẹ̀yà àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.

21. Ìlú ìpẹ̀kun gúsù ti ẹ̀yà Júdà ní Négéfi ní ààlà Édómù niwọ̀nyí:Kabísélì, Édérì, Jágúrì,

22. Kínà, Dímónà, Ádádà,

23. Kédéṣì, Hásórì, Ítina,

24. Sífì, Télémù, Bíálótì,

25. Hasori-Hádátà, Kerioti-Hésírónì (tí í ṣe Hásórì),

26. Ámámù, Sẹ́mà, Móládà,

27. Hasa-Gádà, Hésímónì, Bẹti-Pélétì,

28. Hasari-Ṣúálì, Bíáṣébà, Bísíótíyà,

29. Báálà, Hímù, Ésémù,

30. Elitóládì, a Késílì, Hórímà,

31. Síkílágì, Mádímánà, Sánsánà,

32. Lébáótì, Sílímù, Háínì àti Rímónì, àpapọ̀ ìlú mọ́kàndín ní ọgbọ̀n àti àwọn ìlétò wọn.

33. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹsẹ̀ òkè:Ésítaólì, Sórà, Áṣínà,

34. Sánóà, Eni-Gánímù, Tápúà, Énámù,

35. Jámútì, Ádúlámù, Sókò, Ásekà,

36. Ṣááráímù, Ádítaímù àti Gédérà (tàbí Gérérótíámù), ìlú mẹ́rìnlá àti àwọn ìletò wọn.

37. Sénánì, Hádáṣà, Mígídánì-Gádì,

38. Díléánì, Mísípà, Jókítẹ́lì,

39. Lákísì, Bósíkátì, Égílónì,

40. Kábónì, Lámásì, Kítílísì,

41. Gédérótì, Bẹti-Dágónì, Náámà àti Mákédà, ìlú mẹ́rìndín ní ogún àti ìletò wọn.

42. Líbínà, Étíérì, Áṣánì,

43. Hífítà, Ásínà, Nésíbù,

44. Kéílà, Ákísíbì àti Máréṣà, ìlú mẹ́sàn àti àwọn ìletò wọn. (9)

45. Ékírónì, pẹ̀lú ibùgbé àti àwọn ìletò rẹ̀ tó yí i ká,

46. ìwọ̀-oòrùn Ékírónì, gbogbo èyí tí ń bẹ nítòòsí Áṣídódù, pẹ̀lú àwọn ìletò wọn,

47. Áṣídódù, agbégbé ìlú rẹ̀ àti ìletò; àti Gásà, ìlú rẹ̀ àti ìletò, títí ó fi dé Wádì ti Éjíbítì àti agbégbé òkun ńlá (òkun Mẹditareníà).

48. Ní ilẹ̀ òkè náà:Ṣámírì, Játírì, Sókò,

49. Dánà, Kíríátì-Sánà (tí í se Débírì),

50. Ánábù, Ésítémò, Ánímù,

51. Gósénì, Hólónì àti Gílónì, ìlú mọ́kànlá àti ìletò wọn.

52. Árabù, Dúmà, ṣ Éṣánì,

53. Jánímù, Bẹti-Tápúà, Áfékà,

54. Húmútà, Kíríátì Áríbà (tí í se, Hébúrónì) àti Síori: ìlú mẹ́sàn án àti àwọn ìletò rẹ̀

55. Máónì, Kámẹ́lì, Sífì, Jútà,

56. Jésérẹ́lì, Jókídíámù, Sánóà,

57. Káínì, Gíbíátì àti Tímà: ìlú mẹ́wàá àti àwọn ìletò wọn.

58. Hálíúlì, Bẹti-Súrì, Gédórì,

59. Máárátì, Bẹti-Ánótì àti Élítékónì: ìlú mẹ́fà àti àwọn ìletò wọn.

60. Kiriati Báálì (tí í ṣe, Kiriati Jeárímù) àti Rábà ìlú méjì àti ìletò wọn.

61. Ní asálẹ̀:Bẹti-Árábà, Mídínì, Sékákà,

62. Níbíṣánì, Ìlú Iyọ̀ àti Ẹni-Gẹ́dì, ìlú mẹ́fà àti ìletò wọn.

63. Júdà kò lè lé àwọn ọmọ Jébúsì jáde, tí wọ́n ń gbé ní Jérúsálẹ́mù. Àwọn ará Jébúsì sì ń gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn Júdà títí dí òní.