orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpín Ti Ẹ̀yà Símíónì

1. Gègé kéjì jáde fún ẹ̀yà Símíónì, ní agbo ilé, ní agbo ilé. Ìní wọn sì wà ní àárin ilẹ̀ Júdà.

2. Lára ìpín wọn ní:Béérí Ṣébà (tàbí Ṣẹ́bà), Móládà,

3. Hasari-Ṣúálì, Báláhì, Ésémù,

4. Élítóládì, Bétúlì, Hómà,

5. síkílágì, Bẹti-Mákábótì, Hasari-Súsà,

6. Bẹti-Lébà ati Ṣárúẹ́nì, ìlú wọn jẹ́ mẹ́talá àti ìletò wọn.

7. Háínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì: Ìlú wọn jẹ́ mẹ́rin àti ìletò wọn:

8. Àti gbogbo àwọn agbégbé ìlú wọ̀nyí títí dé Baalati-Béérì (Rámà ní Négéfì).Èyí ni ìní àwọn ọmọ Símíónì, agbo ilé, ní agbo ilé.

9. A mú ogún ìní àwọn ọmọ Símíónì láti ìpín Júdà, nítorí ìpín Júdà pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ. Báyìí ni àwọn ọmọ Símíónì gba ìní wọn ní àárin ilẹ̀ Júdà.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Sébúlónì.

10. Gègé kẹ́ta jáde fún Sébúlunì, ní agbo ilé ní agbo ilé:Ààlà ìní wọn sì lọ títí dé Sárídì.

11. Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Márálà, ó sì dé Dábésẹ́tì, ó sì lọ títí dé Ráfénì odo ní ẹ̀bá Jókíníámù.

12. Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Sérídì sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tábórì, ó sì lọ sí Dábérátì, ó sì gòkè lọ sí Jáfíà.

13. Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Héférì àti Eti-Kásínì, ó sì jáde ní Rímónì, ó sì yí sí ìhà Níà.

14. Ní ibẹ̀, ààlà sì yí ká ní ìhà àríwá lọ sí Hánátónì ó sì pin ní Àfonífojì Ifita Élì.

15. Lára wọn ni Kátatì, Náhalálì, Símírónì, Ìdálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

16. Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sébúlunì, ní agbo ilé agbo ilé.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Ísákárì.

17. Gègé kẹrin jáde fún Ísákárì, agbo ilé ní agbo ilé.

18. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Jésíréélì, Késúlótì, Súnemù,

19. Háfáráímù, Ṣíhónì, Ánáhárátì,

20. Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì,

21. Rémétì, Ẹni-Gánnímù, Ẹni-Hádà àti Bẹ́tì-Pásésì.

22. Ààlà náà sì dé Tábórì, Ṣáhásúmà, àti Bẹti Ṣẹ́mẹ́ṣì, ó sì pin ní Jọ́dánì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rindínlógún àti iletò wọn.

23. Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Áṣíérì

24. Gègé karùnún jáde fún ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.

25. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Hélíkátì, Hálì, Bẹ́tẹ́nì, Ákísáfù,

26. Álàmélékì, Ámádì, àti Míṣálì. Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ààlà náà dé Kámẹ́lì àti Ṣíhórì-Líbínátì.

27. Nígbà náà ni o yí sí ìhà ilà-oòrùn Bẹti-Dágónì, dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ífíta-Élì, ó sì lọ sí àríwá sí Bẹti-Ẹ́mẹ́kì àti Néíélì, ó sì kọjá lọ sí Kábúlì ní apá òsì.

28. Ó sì lọ sí Ábídónì, Réóbù, Hámónì àti Kánà títí dé Sídónì ńlá.

29. Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rámà, ó sì lọ sí ìlú olódi Tirè, ó sì yà sí Hósà, ó sì jáde ní òkun ní ilẹ̀ Ákísíbì,

30. Úmà, Áfẹ́kì àti Réóbù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlélógún àti ìletò wọn.

31. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Áṣíérì, ní agbo ilé agbo ilé.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Náfítalì.

32. Ìpín kẹfà jáde fún Náfítalì, agbo ilé ní agbo ilé:

33. Ààlà wọn lọ láti Hẹ́lẹ́fì àti igi ńlá ní Sááná nímù; kọjá lọ sí Ádámì Nékébù àti Jábínẹ́ẹ́lì dé Lákúmì, ó sì pín ní Jọ́dánì.

34. Ààlà náà gba ìhà ìwọ̀-oòrùn lọ sí Ásínótì, Tabori ó sì jáde ní Húkókì. Ó sì dé Sébúlúnìe ní ìhà gúsù, Ásíẹ́rì ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Jọ́dánì ní ìhà ìlà-oòrùn.

35. Àwọn ìlú olódi sì Sídímù, Sérì, Hámátì, Rákátì, Kínérétì,

36. Ádámà, Rámà Hásórì,

37. Kédéṣì, Édíréì, Ẹ́ní-Hásórì,

38. Írónì, Mígídálì-Élì, Hórémù, Bẹ́tì-Ánátì àti Bẹ́tì-Sẹ́mẹ́ṣì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún àti ìletò wọn.

39. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Náfitalì, ní agbo ilé sí agbo ilé.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Dánì

40. Ìbò keje jáde fún ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé ní agbo ilé.

41. Ilẹ̀ ìní wọn nì wọ̀nyí:Sórà, Éṣtaólì, Írí-Ṣẹ́mẹ́sì,

42. Ṣáálábínì, Áíjálónì, Ítílà,

43. Élónì, Tímínà, Ékírónì,

44. Élítékè, Gíbétónì, Báálátì,

45. Jéúdì, Béné-Bérákì, Gátí-Rímónì,

46. Mé Jákónì àti Rákónì, pẹ̀lú ilẹ̀ tí ó kọjú sí Jópà.

47. (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dánì ní ìsoro láti gba ilẹ̀-ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Lẹ́ṣẹ́mù, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Lẹ́sẹ́mù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì orúkọ baba ńlá wọn).

48. Àwọn ìlú wọ̀n yí àti ìletò wọn ní ìní ẹ̀yà Dánì, ní agbo ilé agbo ilé.

Ìpín Fún Ẹ̀yà Jósúà.

49. Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Ísírẹ́lì fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ìní ní àárin wọn

50. Bí Olúwa ti pàṣẹ, wọ́n fún-ún ni ìlú tí ó béèrè fún—Tímínátì Sérà ní ìlú òkè Éfúráímù. Ó sì kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé ibẹ̀.

51. Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Élíásárì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Ísírẹ́lì fi ìbò pín ní Sílò ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.