orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Májẹ̀mu Di Ọ̀tun Ní Sékémù

1. Nígbà náà ni Jóṣúà pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ ní Ṣékémù. Ó pe àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, onídájọ́ àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.

2. Jóṣúà sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Térà bàbá Ábúráhámù àti Náhórì ń gbé ní ìkọjá odò, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.

3. Ṣùgbọ́n mo mú Ábúráhámù baba yín kúrò ní ìkọjá odò mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kénánì, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Ísáákì,

4. Èmi sì fún ní Ísáákì, mo fún ní Jákọ́bù àti Ísáù, mo sì fún Ísáù ní ilẹ̀ orí òkè Séírì, Ṣùgbọ́n Jákọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

5. “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mósè àti Árónì, mo sì yọ Éjíbítì lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

6. Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Éjíbítì, ẹ wá sí òkun, àwọn ará Éjíbítì lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun pupa.

7. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́.

8. “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò ní wájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.

9. Nígbà tí Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, múra láti bá Ísírẹ́lì jà, ó ránṣẹ́ sí Bálámù ọmọ Béóríù láti fi yín bú.

10. Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

11. “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò. Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

12. Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà ólífì tí ẹ kò gbìn.’

14. “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò àti ní Éjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

16. Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà.!

17. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Éjíbítì, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárin gbogbo orílẹ̀ èdè tí a là kọjá.

18. Olúwa sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Ámórì, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin Olúwa, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”

19. Jóṣúà sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, Kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

20. Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀ èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

21. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Jóṣúà pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”

22. Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.”Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23. Nígbà náà ni Jóṣúà dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárin yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”

24. Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Jóṣúà pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọràn sí.”

25. Ní ọjọ́ náà Jóṣúà dá májẹ̀mu fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Sékémù.

26. Jóṣúà sì kọ gbogbo ìdàhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi Óákù ní ẹ̀bá ibi-mímọ́ Olúwa.

27. “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run yín.”

Ikú Jóṣúà Àti Élíásérì

28. Lẹ́yìn náà ni Jóṣúà jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀-ìní rẹ̀,

29. Lẹ́yìn nǹkàn wọ̀nyí, Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110)

30. Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Tíminátì Sérà ni ilẹ̀ orí òkè Éfúráímù, ní ìhà àríwá Òkè Gááṣì.

31. Ísírẹ́lì sì sin Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbààgbà tí ó pẹ́ ju Jóṣúà lọ àti àwọn tó ti rí ohun gbogbo tí Olúwa ti ṣe fún Ísírẹ́lì.

32. Egungun Jóṣéfù, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Éjíbítì, ni wọ́n sin ní Ṣékémù ní ìpín ilẹ̀ tí Jákọ́bù rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hámórì, baba Ṣékémù. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀-ìní àwọn ọmọ Jósẹ́fù.

33. Élíásérì ọmọ Árónì sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gíbéà, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Fínéhásì ní òkè ilẹ̀ Éfúráímù.