Olúwa sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Jóṣúà fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jẹ́ríkò.