orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Orúkọ Àwọn Ọba Tí A Ṣẹ́gun.

1. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

2. Síhónì ọba àwọn Ámorì,tí ó jọba ní Hésíbónì. Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì.

3. Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà.

4. Àti agbégbé Ógù ọba Básánì,ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.

5. Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì.

6. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

7. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: