orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburúmá ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;

2. Nítorí ọkàn wọn ń gbérò ohun búburú,ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

3. Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́nípa òye sì ni ó ti fìdí múlẹ̀;

4. Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kúnpẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

5. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára síi

6. Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:nínú ìsẹ́gún ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

7. Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrèàti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

8. Ẹni tí ń pète ibini a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.

9. Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10. Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmúbáwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!

11. Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ síbi ikú là;fa àwọn tó ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n lọ síbi ìparun padà.

12. Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkankan nípa èyí,”ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsíi? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́?Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13. Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.

14. Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹbí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọìrètí rẹ kì yóò sì já sófo.

15. Má ṣe ba ní ibùba bí i arúfin dé ilé Olódodo,má ṣe kó ibùgbé è rẹ̀ lọ;

16. Nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbàméje, yóò tún padà dìde ṣáá ni,ṣùgbọ́n ìdàámú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17. Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀

18. àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínúyóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19. Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibitàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,

20. nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájúa ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

21. Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,má sì ṣe dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun

22. nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Mìíràn

23. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́nláti ṣe ojúṣàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:

24. Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì kọ̀ ọ́.

25. Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26. Ìdáhùn òtítọ́ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

27. Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹsì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28. Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí,tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.

29. Má ṣe wí pé, “Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30. Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn;

31. ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,koríko ti gba gbogbo oko náà

32. Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsímo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;

33. oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi

34. Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalèàti àìní bí olè.