orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sànju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

2. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.

3. Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúràṢùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.

4. Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibiòpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.

5. Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náàẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.

6. Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbóòbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.

7. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòómélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!

8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohungbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.

9. Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.

10. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóyeju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.

11. Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.

12. Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

13. Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire,ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.

14. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún ominítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

15. Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kóríra méjèèjì.

16. Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrèníwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n?

17. Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.

18. Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúraó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.

19. Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.

20. Ènìyàn aláyìídáyidà ọkàn kì í gbèrúẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.

21. Láti bí aláìgbọ́n lọmọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkànkò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.

22. Ọkàn tí ó túká jẹ́ ogún gidiṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.

23. Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀láti yí ìdájọ́ po.

24. Olóyè ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájúṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.

25. Aláìgbọ́n ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.

26. Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.

27. Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọènìyàn olóye sì máa ń ní ṣùúrù.

28. Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọgbọ́n bí ó bá dákẹ́àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.