orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.

2. Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òyeṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀.

3. Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dénígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.

4. Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìnṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn.

5. Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburútàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.

6. Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

7. Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀.

8. Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùnwọ́n ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.

9. Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.

10. Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.

11. Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọnwọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

12. Sáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéragaṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

13. Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́òun náà ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.

14. Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsànṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.

15. Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.

16. Ẹ̀bùn máa ń sí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùna sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.

17. Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàretítí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo.

18. Ìbò dídì máa ń parí ìjàa sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.

19. Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ,ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe.

20. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.

21. Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú,àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́.

22. Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwa.

23. Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.

24. Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parunṢùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin.