orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́gbọ́n ọmọ pa àṣẹ baba rẹ̀ mọ́ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò fetí sí ìbáwí.

2. Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn àwọn ohun rereṣùgbọ́n, aláìsòótọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti inú ìwà ipá.

3. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù-gbàù yóò parun.

4. Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkankan,ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.

5. Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.

6. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòótọ́ inú,ṣùgbọ́n ìwà búburú sí ẹlẹ́ṣẹ̀ nípò.

7. Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkankanẹlòmííràn díbọ́n bí i talákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

8. Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ṣùgbọ́n talákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

12. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14. Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.

15. Òye pípé ń mú ni rí ojú rereṢùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17. Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámúṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá.

18. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú,ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19. Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkànṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20. Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21. Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22. Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23. Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wáṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24. Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí.

25. Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùnṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.