orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkànṢùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

2. Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dà bí i pé ó dára lójú ara rẹ̀Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.

3. Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.

4. Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

5. Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

6. Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

7. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.

8. Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodoju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú.

9. Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

10. Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síiẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀.

11. Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12. Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13. Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.

14. Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16. Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọàti láti yan òye dípò o fàdákà!

17. Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

18. Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú,

19. ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njújù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

20. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire,ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.

21. Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóyeọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.

22. Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i,ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.

23. Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.

24. Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyinó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.

25. Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyànṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.

26. Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún unnítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.

27. Ènìyàn búburú ń pèteọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.

28. Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.

29. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

30. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.

31. Ewú orí jẹ́ ògoìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.

32. Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.

33. A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ,ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.