orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọgbọ́n Ń Fi Ìpè Sítapè

1. Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?

2. Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nàní ìkòríta, ní ó dúró;

3. Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:

4. Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,

5. Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.

6. Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ;Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,

7. Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,nítorí ètè mi kórìíra ibi.

8. Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́,kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀

9. Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.

10. Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,

11. Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ,kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e.

12. “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

13. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkóòríra ibimo kóríra ìgbéraga àti agídí,ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

14. Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmimo ní òye àti agbára.

15. Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkósotí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára

16. Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkósoàti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.

17. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn miàwọn tí ó sì wá mi rí mi.

18. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wàỌrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.

19. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.

20. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,ní ojú ọ̀nà òtítọ́,

21. mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mimo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

22. “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;

23. A ti yàn mí láti ayérayé,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.

24. Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí minígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú;

25. kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,

26. kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.

27. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,

28. Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókètí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀,

29. Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkunkí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

30. Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀

31. mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dámo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

32. “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́

33. fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n;má ṣe pa á tì sápá kan.

34. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi,tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́,tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi.

35. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyèó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.

36. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ láragbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú.”