orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọgbọ́n Ni Ó Ga Jùlọ

1. Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetí sílẹ̀ kí o sì ní òye sí i

2. Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooroNítorí náà má ṣe kọ ìkọ́ni mi sílẹ̀

3. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi

4. Ó kọ́ mi ó sì wí pé“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.

5. Gba ọgbọ́n, gba òye,Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀

6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ.

7. Ọgbọ́n ni ó ga jù; Nítorí náà gba ọgbọ́n.Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye

8. Gbé e ga, yóò sì gbé ọ gadìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

9. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹyóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10. Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

11. Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́nmo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.

12. Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀.

13. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburútàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

15. Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ

16. Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú

17. Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurúwọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

18. Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùntí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí

19. ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

20. Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi

21. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójúpa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;

22. Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọnàti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn

23. Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́Nítorí òun ni oríṣun ìyè,

24. mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.

25. Jẹ́ kí ojú ù rẹ máa wo iwájú,jẹ́ kí ìwo ojú ù rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sáá.

26. Kíyèsí ìrìn ẹṣẹ̀ rẹsì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan

27. má ṣe yà sọ́tùn-ún tàbí ṣósìpa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.