orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìkìlọ̀ Nítorí Àwọn Asẹ́wó

1. Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.

2. Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yètọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ

3. Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹunkọ wọ́n sí inú ọkàn rẹ.

4. Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”sì pe òye ní ìbátan rẹ;

5. wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,kúrò lọ́wọ́ ìyàwó onírìnkurìn àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.

6. Ní ojú fèrèsé ilé è mimo wo ìta láti ojú ù fèrèsé.

7. Mo rí i láàrin àwọn aláìmọ́kanmo sì kíyèsí láàrin àwọn ọ̀dọ́kùnrin,ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.

8. Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbérè obìnrin náà,ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀

9. ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,bí òkùnkùn ṣẹ ń bo ni lára.

10. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,ó múra bí aṣẹ́wó pẹ̀lú ètè búburú.

11. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;

12. bí ó ti ń já níhìn ín ní ó ń já lọ́hùn úngbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)

13. Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnupẹ̀lú ojú dídín ó wí pé:

14. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

15. Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ;mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

16. Mo ti tẹ́ ibùṣùn mipẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.

17. Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mibí i míra, álóè àti kínámónì.

18. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

19. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.

20. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

21. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

22. Kíákíá ni ó tẹ̀lé ebí i màlúù tí ń lọ sí odò ẹranbí àgbọ̀nrín tí ó fẹ́ kẹsẹ̀ bọ pàkúté

23. títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,Láì mọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

24. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mifọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

25. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

26. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

27. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààra sí iṣà òkú,tí ó lọ tààra sí àgbàlá ikú.