orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.

2. Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.

3. Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nàó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.

4. Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

5. Ètè àwọn olóye já sí èrèbí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.

6. Ìṣúra tí a kójọ nípaṣẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹkùn ikú.

7. Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.

8. Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.

9. Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùléju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.

10. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibialádùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

11. Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n.

12. Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburúó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.

Ìṣúra Ẹni Tí Ó Gbọ́n

13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.

14. Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,dẹ́kun ìbínú líle.

15. Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

16. Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.

17. Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà:ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.

18. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.

19. Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.

20. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.

21. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.

22. Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.

23. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

24. Agbéraga àti alágídí ènìyàan ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,tí ń hùwà nínú àdábọwọ́ ìgbéraga.

25. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.

26. Ó ń fi ìlara ṣojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.

27. Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:mélòómélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà-ibi?

28. Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.

29. Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:ṣùgbọ́n ẹni ìdúró-ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

30. Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.

31. A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.