orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe yangàn nítorí ọ̀lanítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

2. Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹàní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.

3. Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwoṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

4. Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú?

5. Ìbániwí gbangba sànju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

6. Ọgbẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ṣe é gbẹ́kẹ̀léṣùgbọ́n ọ̀tá máa ń fẹnu-koni-lẹ́nu púpọ̀.

7. Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yóṣùgbọ́n òróòro gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8. Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.

9. Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkànbẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó Ṣàkóso.

10. Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀,má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdàámú dé bá ọó sàn kí o jẹ́ aládúúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà síni.

11. Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn minígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.

12. Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pamọ́ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí kàkàkí ó dúró ó tẹ̀ṣíwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

13. Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjòjìfi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oní ìṣekúṣe.

14. Bí ènìyàn kan ń kígbe e ṣúre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀a ó kà á sí bí èpè.

15. Àyà tí ó máa ń jà dàbíọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;

16. dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kuntàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.

17. Bí irin tí ń pọ́n irin múbẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.

18. Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.

19. Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò óbẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.

20. Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn ríbẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.

21. Iná fún fàdákà iná ìlérú fún wúrà,ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.

22. Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,fi ọmọ odó gún-un bí èlùbọ́ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.

23. Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wàbojú tó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;

24. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títíadé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

25. Nígbà tí a bá kó koríko jọ láti orí òkè

26. àwọn àgùntàn yóò pèṣè aṣọ fún ọ,àti ewúrẹ́ yóò pèṣè owó oko.

27. Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíkì ewúrẹ́láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹàti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.