orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padàṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

2. Ahọ́n ọlọgbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jádeṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

3. Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

4. Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyèṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

5. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n.

6. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

7. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

8. Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn.

9. Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

10. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

11. Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú Olúwamélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.

12. Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí:kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

13. Inú dídùn máa ń mú kí ojú túkáṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.

14. Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.

15. Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi,ṣùgbọ́n ọkàn tí ń dunnú a máa Jàṣè ṣáá.

16. Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wàju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

17. Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wàsàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.

18. Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

19. Ẹ̀gún dí ọ̀nà ọ̀lẹṣùgbọ́n pópónà tí ń dán ni ti àwọn dídúró ṣinṣin.

20. Ọlọgbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ kẹ́gàn baba rẹ̀.

21. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

22. Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràwà.

23. Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó báa muọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

24. Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọgbọ́nláti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.

25. Olúwa fa ilé onígbéraga ya lulẹ̀,Ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó mọ́ láìyẹ̀.

26. Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú,

27. Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.

28. Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wòṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

29. Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

30. Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.

31. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

32. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi.

33. Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.