orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwíyóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

2. Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.

3. Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́

4. Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini,ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.

5. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládúgbò rẹ̀ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

6. Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹkùn rẹ̀ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.

7. Olódodo ń ṣaápọn nípa ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tálákà,ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó kan ènìyàn búburú nínú irú rẹ̀.

8. Àwọn Ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè,ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

9. Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́naláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.

10. Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣinwọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.

11. Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínúṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

12. Bí olórí bá fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.

13. Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.

14. Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo.

15. Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́nṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀.

16. Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn.

17. Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíàyóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.

18. Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà.Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.

19. A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.

20. Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀?Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.

21. Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeréyóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.

22. Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè,Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.

23. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

24. Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.

25. Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùnṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.

26. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo,ṣùgbọ́n láti ọdọ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.

27. Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́:ènìyàn búburú kórìíra olódodo.