Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”