orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpín Ti Àwọn Ọmọ Ogun.

1. Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọrọrún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣoṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin (24,000) ọkùnrin.

2. Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ni fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jáṣóbéámù ọmọ Ṣábídiélì àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ólé ẹgbàá mẹ́rin ní ó wà ní abẹ́ (24,000) ìpín tirẹ̀.

3. Ó jẹ́ ìran ọmọ pérésì àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.

4. Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

5. Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).

6. Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀.

7. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

8. Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.

9. Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Írà ọmọ Íkéṣì, ará Tékóì. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

10. Ẹ̀kéje fún oṣù kéje jẹ́ Hélésì ará Pélónì, ará Éfíráímù. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín Rẹ̀.

11. Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

12. Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́. Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

13. Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹ́wàá jẹ́ Máháráì ará Nétófátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.

14. Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Bénáyà ará pírátónì ará Éfíráímù ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

15. Ìkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Hélídáì ará Nétófátì láti ìdílé Ótíníélì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.

Àwọn Ìjòyè Ti Ẹ̀yà Náà.

16. Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Ísírẹ́lì:lórí àwọn ará Réúbẹ́nì: Éliésérì ọmọ Ṣíkírì;lórí àwọn ará Ṣíméónì: Ṣéfátíyà ọmọ Mákà;

17. lórí Léfì: Háṣábíà ọmọ Kémúélì;lori Árónì: Ṣádókù;

18. lórí Júdà: Élíhù arákùnrin Dáfídì;lóri Ísákárì: Ómírì ọmọ Míkáélì;

19. lórí Ṣébúlúnì: Íṣímáíà ọmọ Óbádáyà;lori Náfitalì: Jérímótì ọmọ Áṣíríélì;

20. lórí àwọn ará Éfíráímù: Hòṣéà ọmọ Áṣásíà;lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè: Jóélì ọmọ Pedáyà;

21. lorí ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní Gílíádì: Ìdó ọmọ Ṣékáráyà;lórí Bẹ́ńjámínì: Jásíélì ọmọ Ábínérì;

22. lórí Dánì: Áṣárélì ọmọ Jéróhámù.Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

23. Dáfídì kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítori Olúwa ti ṣe ìlerí lati ṣe Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

24. Jóábù ọmọ Ṣérúyà bẹ̀rẹ̀ sí ní kàwọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Ísírẹ́lì nipaṣẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọọ́ sínu ìwé ìtàn ayé ti ọba Dáfídì.

Àwọn Alábojútó Ọba.

25. Áṣímáfétì ọmọ Ádíélì wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jónátanì ọmọ Úṣíà wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìlètò àti àwọn ilé ìṣọ́.

26. Ésírì ọmọ kélúbì wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.

27. Ṣíméhì ará Rámátì wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.Ṣábídì ará Ṣífímì wà ní ìdí mímú jáde ti èṣo àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.

28. Bálì Hánánì ará Gédérì wà ní ìdi Ólífì àti àwọn igi Ṣíkámórè ní apá ìhà ìwọ̀ oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.Jóáṣì wà ní ìdí fífún ni ní òróró Ólífì.

29. Ṣítíráì ará Ṣárónì wà ní idi fífi ọwọ́ ẹran jẹ ko ní Ṣárónì.Ṣáfátì ọmọ Ádíláì wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́-ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.

30. Óbílì ará Íṣímáélì wà ní ìdí àwọn ìbákasíẹ.Jéhidéísì ará Mérónótì wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

31. Jáṣíṣì ará Hágírì wà ní ìdi àwọn agbo-ẹran.Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dáfídì.

32. Jónátanì, arákùnrin Dáfídì jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jéhíélì ọmọ Hákímónì bojútó àwọn ọmọ ọba.

33. Áhítófélì jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba.Húsáì ará Áríkì jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.

34. Jéhóíádà ọmọ Bẹnáyà àti nípaṣẹ̀ Ábíátárì jọba rọ́pò Áhítófélì.Jóábù jẹ́ olórí ọmọ ogun ọba.