orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Akọrin

1. Pẹ̀lúpẹ̀lú Dáfídì àti àwọn olórí àwọn ọmọ ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì fún ìsìn àsọtẹ́lè, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin àti kínbálì. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí:

2. Nínú àwọn ọmọ Ásáfù:Ṣákúrì, Jóṣẹ́fù Nétanáíà àti Ásárélà, àwọn ọmọ Ásáfù ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Ásáfù, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba.

3. Gẹ́gẹ́ bí ti Jédútúnì, nínú àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀:Gédálià, Ṣérì, Jéṣáíà, Ṣíméhì Háṣábíà àti Mátítíyà, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti lati yin Olúwa:

4. Gẹ́gẹ́ bí ti Hémánì, nínú àwọn ọmọ Rẹ̀:Búkíà, Mátaníyà, Usíélì, Ṣúbáélì àti Jérímótì; Hánáníyà, Hánánì, Élíátà, Gídáítì àti Rámámútì Ésérì; Jósíbékáṣà, Málótì, Hótírì àti Máhásíótì.

5. Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hémánì àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta.

6. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn bàba wọn fún ohun èlò orin ilé Olúwa, pẹ̀lú Kínbálì, Písálítérì àti dùùrù, fún Ìsìn ilé Olúwa. Ásáfù, Jédútúnì, ọba.

7. Àwọn ìdilé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún Olúwa, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ (288).