orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Òmíràn Ẹ̀yà Júdà

1. Àwọn ọmọ Júdà:Fárésì, Hésírónì, Kárímì, Húrì àti Ṣóbálì.

2. Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà.

3. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù:Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì

4. Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

5. Áṣárì bàbá Jékóà sì ní aya méjì, Hélà àti Nárà.

6. Nárà sì bí Áhúsámù, Héférì Téménì àti Háhásítarì. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Nátà.

7. Àwọn ọmọ Hélà:Ṣérétì Ṣóárì, Étanì,

8. Àti kósì ẹnítí ó jẹ́ baba Ánúbì àti Hásóbébà àti ti àwọn Ẹ̀yà Áháríhélì ọmọ Hárúmù.

9. Jábésì sì ní olá ju àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá Rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jábésì wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.”

10. Jábésì sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, “Áà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbégbé mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mí mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀

11. Kélúbù arákùnrin ṣúà, sì jẹ́ baba Méhírì, ẹni tí ó jẹ́ baba Ésítónì.

12. Ésítónì sì jẹ́ baba Bétí-ráfà, Páséà àti Téhína ti baba ìlú Náhásì. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Rékà.

13. Àwọn ọmọ Kénásì:Otíníẹ́lì àti Ṣéráíà.Àwọn ọmọ Ótiníẹ́lì:Hátatì àti Méónótaì.

14. Méónótaì sì ni baba Ófírà.Ṣéráíà sì jẹ́ baba Jóábù,baba Géhárásínù. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn onísọ́nà niwọ́n.

15. Àwọn ọmọ kálébù ọmọ Jéfúnè:Irú, Élà, àti Námù.Àwọn ọmọ Élà:Kénásì.

16. Àwọn ọmọ Jéhálélélì:Ṣífù, ṣífà, Tíríà àti Ásárélì.

17. Àwọn ọmọ Ésírà:Jétẹ́rì, Mérédì, Éférì àti Jálónì. Ọ̀kan lára àwọn aya Mérédì sì bí Míríámù, ṣámáì àti Íṣíbà baba Éṣítémóà.

18. Aya Rẹ̀ Jéhúdijà sì bí Jérédì baba Gédórì, Hébérì baba sókè àti Jékútíẹ́lì bàbá Sánóà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin ọmọ Bítíà ẹni ti Mérédì ti fẹ́.

19. Àwọn ọmọ aya Hódíyà arábìnrin Náhámù:Baba Kéílà ará Gárímì, àti Ésítémóà àwọn ará Mákà.

20. Àwọn ọmọ Símónì:Ámónì, Rínà, Beni-Hánánì àti Tílónì.Àwọn ọmọ Íṣì:Ṣóhítì àti Beni-Sóhétì.

21. Àwọn ọmọ Ṣélà ọmọ Júdà:Érì baba Lékà, Ládà baba Máréṣà àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń wun aṣọ oníṣẹ́ ní Bẹti-Áṣíbéà.

22. Tókímù, ọkùnrin kósébà, àti Jóáṣì àti sáráfù, olórí ní Móábù àti Jáṣúbì Léhémù. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́).

23. Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Nítaímù àti Gédérà; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń sisẹ́ fún ọba.

Síméónì.

24. Àwọn Ọmọ Síméónì:Némúélì, Jámínì, Járíbì, Ṣérà àti Ṣáúlì;

25. Ṣálúmù sì jẹ́ ọmọ Ṣáúlì, Míbísámù ọmọ Rẹ̀ Miṣima ọmọ Rẹ̀.

26. Àwọn ọmọ Míṣímà:Hámúélì ọmọ Rẹ̀ Sákúrì ọmọ Rẹ̀ àti Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀.

27. Síméì sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Júdà.

28. Wọ́n sì ń gbé ní Béríṣébà, Móládà, Hásárì Ṣúálì,

29. Bílà, Ésémù, Tóládì,

30. Bétúélì, Hórímà, Síkílágì,

31. Bẹti máríkóbótì Hórímà; Hásárì Ṣúsímù, Bẹti Bírì àti Ṣáráímì. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dáfídì,

32. agbégbé ìlú wọn ni Étamù Háínì, Rímónì, Tókénì, Áṣánì àwọn ìlú márùnún

33. Àti gbogbo ìletò tí ó wà ní agbégbé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti dé Bálì Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn, wọ́n sì pa ìwé ìtàn ìdílé mọ́.

34. Méṣóbábù Jámilékì, Jóṣáì ọmọ Ámásáyà,

35. Jóẹ́lì, Jéhù ọmọ Jósíbíà, ọmọ Ṣéráíáyà, ọmọ Ásíẹ́lì,

36. Àti pẹ̀lú Élíóénáì, Jákóbà, Jéṣóháiyá, Ásáíyà, Ádíélì, Jésímíẹ́lì, Bénáíyà,

37. Àti Ṣísà ọmọ ṣífì ọmọ Álónì, ọmọ Jédáíyà, ọmọ Ṣímírì ọmọ Ṣémáíyà.

38. Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn. Àwọn ìdílé sì pọ̀ síi gidigidi,

39. Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gédórì. Lọ títí dé ìlà òrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn

40. Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ará Ámù ni ó ń gbé bẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

41. Ọkùnrin tí a kọ orúkọ Rẹ̀ sókè wà ní ọjọ́ Hésékíà ọba Júdà àti àwọn ibùgbé wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Máhúnì ẹni tí ó wà níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátapáta. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ẹ̀rí títí di òníyìí. Nígbà náà wọ́n sì ń gbé ní iye wọn, nítorí pé koríko wà fún àwọn agbo ẹran wọn.

42. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Síméónì, sin pẹ̀lú Pélátíà, Néáríà, Réfáíà àti Úsíélì, àwọn ọmọ Íṣì, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Ṣéírì.

43. Wọ́n sì pa àwọn ará Ámálékì tí ó kù àwọn tí ó ti sá lọ, wọ́n sì ti ń gbé bẹ̀ láti òní yìí.