orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ṣọ́ọ̀lù Gba Ẹ̀mí Ara Rẹ̀

1. Nísinsin yìí, àwọn ará Fílístínì dojú ìjà kọ Ísírẹ́lì, Àwọn ará ísírélì sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí ọri òkè Gílíbóà

2. Àwọn ará Fílístínì sí lépa Sáúlù gidigidi àti àwọn ọmọ Rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ Rẹ̀. Jónátanì, Ábínádábù àti Málíkíṣúà.

3. Ìjà náà sì ń gbóná síi yí Sáúlù ká. Nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́.

4. Ṣọ́ọ̀lù sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ pé, Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é; Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà tirẹ̀ ó sì subú lé e.

5. Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Ṣọ́ọ̀lù ti kú, òhun pẹ̀lú subú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ Rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú gbogbo ilé Rẹ̀ sì kú lápapọ̀.

7. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ ogun ti sálọ àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Fílístínì wá, wọ́n sì gba ipò wọn.

8. Ní ọjọ́ kejì, Nígbà tí àwọn ará Fílístínì wá láti kó okú, wọ́n rí Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gílíbóà.

9. Wọ́n bọ́ ọ láọ (Stripped), wọ́n sì gbé orí Rẹ̀ àti ìhámọ́ra Rẹ̀. Wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ kákiri ilẹ̀ Àwọn ará Fílístínì láti kéde ìròyìn náà láàrin àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn.

10. Wọ́n gbé ìhámọ́ra Rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìsà wọn, wọ́n sì fi orí Rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dágónì.

11. Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jábésì Gíléádì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Fílístínì ṣe fún Ṣọ́ọ̀lù,

12. Gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ Rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jábésì. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi ńlá ní Jábésì, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.

13. Ṣọ́ọ̀lù kú nítorí kò se òtítọ́ sí Olúwa: Kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà.

14. Kò sì bèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dáfídì ọmọ Jésè.