orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Léfì

1. Àwọn ọmọ Léfì:Gérísónì, Kóhátì àti Mérárì.

2. Àwọn ọmọ Kóhátì:Ámírámù, Ísárì, Hébírónì, àti Húsíélì.

3. Àwọn ọmọ Ámírámù:Árónì, Mósè àti Míríámù.Àwọn ọmọkùnrin Árónì:Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.

4. Élíásérì jẹ́ baba Fínéhásì,Fínéhásì baba Ábísúà

5. Ábísúà baba Búkì,Búkì baba Húṣì,

6. Húsì baba Ṣéráhíà,Ṣéráhíà baba Méráíótì,

7. Méráíótì baba Ámáríyà,Ámáríyà baba Áhítúbì

8. Álítúbù bàbá Ṣádókù,Ṣádókù baba Áhímásì,

9. Áhímásì baba Áṣáríyà,Ásáríyà baba Jóhánánì,

10. Jóhánánì baba Áṣáríyà (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Sólómónì kọ́ sí Jérúsálẹ́mù),

11. Áṣáríyà baba ÁmáríyàÁmáríyà baba Áhítúbì

12. Áhítúbì baba Ṣádókù.Ṣádókù baba Ṣálúmù,

13. Ṣálúmù baba Hílíkíyà,Hílíkíyà baba Áṣáríyà,

14. Áṣáríyà baba Ṣéráíà,pẹ̀lú Ṣéráíà baba Jéhósádákì

15. A kó Jéhósádákì lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Júdà àti Jérúsálẹ́mù kúrò ní ìlú nípaṣẹ̀ Nebukadinésárì.

16. Àwọn ọmọ Léfì:Gérísónì, kóhátì àti Mérárì.

17. Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Géríṣónì:Líbínì àti Ṣíméhì.

18. Àwọn ọmọ Kéhátì:Ámírámù, Íṣárì, Hébírónì àti Húsíélì.

19. Àwọn ọmọ Mérárì:Máhílì àti Múṣì.Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Léfì tí a kọ ní ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20. Ti Gérísómù:Líbínì ọmọkùnrin Rẹ̀, JéhátìỌmọkùnrin Rẹ̀, Ṣímà ọmọkùnrin Rẹ̀,

21. Jóáhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Idò ọmọkùnrin Rẹ̀, Ṣéráhì ọmọkùnrin Rẹ̀àti Jéátéráì ọmọkùnrin Rẹ̀.

22. Àwọn ìran ọmọ Kóhátì:Ámínádábù ọmọkùnrin Rẹ̀, Kóráhì ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

23. Élikánà ọmọkùnrin Rẹ̀,Ébíásáfí ọmọkùnrin Rẹ̀,Ásírì ọmọkùnrin Rẹ̀.

24. Táhátì ọmọkùnrin Rẹ̀, Úríélì ọmọkùnrin Rẹ̀,Úsíáhì ọmọkùnrin Rẹ̀ àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Rẹ̀.

25. Àwọn ìran ọmọ Élíkánáhì:Ámásáyì, Áhímótì

26. Élíkáná ọmọ Rẹ̀, Ṣófáì ọmọ Rẹ̀Náhátì ọmọ Rẹ̀,

27. Élíábù ọmọ Rẹ̀,Jéríhámù ọmọ Rẹ̀, Élíkáná ọmọ Rẹ̀àti Ṣámúẹ́lì ọmọ Rẹ̀.

28. Àwọn ọmọ Ṣámúẹ́lì:Jóẹ́lì àkọ́bíàti Ábíjà ọmọẹlẹ́ẹ̀kejì.

29. Àwọn ìran ọmọ Mérárì:Máhílì, Líbínì ọmọ Rẹ̀.Ṣíméhì ọmọ Rẹ̀, Úṣáhì ọmọ Rẹ̀.

30. Ṣíméà, ọmọ Rẹ̀ Hágíáhì ọmọ Rẹ̀àti Ásáíáhì ọmọ Rẹ̀.

Ilé Tí A kọ́ Fún Àwọn Olórin

31. Èyí ní àwọn ọkùnrin Dáfídì tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sínmìn níbẹ̀.

32. Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin ńiwájú Àgọ́ ìpàdé títí tí Ṣólómónì fi kọ́ ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n se iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33. Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kóhátítè:Hémánì olùkọrin,ọmọ Jóẹ́lì, ọmọ Ṣámúẹ́lì,

34. Ọmọ Élíkánáhì ọmọ Jéróhámù,ọmọ Élíéli, ọmọ Tóhà

35. Ọmọ Ṣúfì, ọmọ Élíkáná,ọmọ Máhátì, ọmọ Ámásáyì,

36. Ọmọ Élíkánà, ọmọ Jóẹ́lì,ọmọ Ásárááhì, ọmọ Ṣéfáníáhì

37. Ọmọ Táhátì, ọmọ Áṣírì,ọmọ Ébíásáfì ọmọ Kóráhì,

38. ọmọ Íṣíhárì, ọmọ Kóhátìọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì;

39. Hémánì sì darapọ̀ mọ́ Ásátì, ẹni tí Ó sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀:Ásátì ọmọ bérékíáhì, ọmọ Ṣíméà,

40. Ọmọ Míkáélì, ọmọ Bááséíáhì,ọmọ Málíkíjáhì

41. Ọmọ Étínì,ọmọ Ṣéráhì, ọmọ Ádáyà,

42. Ọmọ Étanì, ọmọ Ṣímáhì,ọmọ Ṣíméhì,

43. Ọmọ Jáhátì,ọmọ Gérísíónì, ọmọ Léfì;

44. láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Mérárì wà ní ọwọ́ òsì Rẹ̀:Étanì ọmọ Kísì, ọmọ Ábídì,ọmọ Málúkì,

45. Ọmọ Háṣábíáhìọmọ Ámásáyà, ọmọ Hítíkíáhì,

46. Ọmọ Ámíṣì ọmọ Bánì,ọmọ Ṣémérì,

47. Ọmọ Máhílì,ọmọ Múṣì, ọmọ Mérárì,ọmọ Léfì.

48. Àwọn Léfì ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yókù ti Àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.

49. Ṣùgbọ́n Árónì àti àwọn ìran ọmọ Rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a se ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti paláṣẹ.

50. Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì:Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀,Ábísúà ọmọ Rẹ̀,

51. Búkì ọmọ Rẹ̀,Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,

52. Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,

53. Ṣádókù ọmọ Rẹ̀àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.

54. Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):

55. A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

56. Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.

57. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,

58. Hílénì Débírì,

59. Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.

60. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.

61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.

62. Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.

63. Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní.

64. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65. Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66. Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn.

67. Ní òkè orílẹ̀ èdè Éfíráímù, a fún wọn ní Ṣékémù (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Géṣérì

68. Jókíméámù, Bétì-Hórónì.

69. Áíjálónì àti Gátì Rímónì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70. Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ádérì àti Bíléámù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kóhátítè.

71. Àwọn ará Géríṣónítè gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè wọ́n gba Gólánì ní Básánì àti pẹ̀lú Áṣítarótì, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72. Láti ẹ̀yà Ísákárìwọ́n gba Kádéṣì, Dábérátì

73. Rámótì àti Ánénù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

74. Láti ẹ̀yà Áṣérìwọ́n gba Máṣálì Ábídónì,

75. Húkokì àti Réhóbù lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

76. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Náfítalìwọ́n gba Kédésì ní Gálílì, Hámoníà Kíríátaímù, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77. Àwọn ará Mérárì (ìyókù àwọn ará Léfì) gbà nǹkan wọ̀nyí:Láti ẹ̀yà Sébúlúnìwọ́n gba Jókíneámù, Kárítahì, Rímónò àti Tábórì, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78. Láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì rékọjá Jódánì ìlà oòrùn Jẹ́ríkòwọ́n gba Bésérì nínú ihà Jáhíṣáhì,

79. Kédémótì àti Méfátù, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko, tútù wọn;

80. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gádìwọ́n gba Rámóà ní Gílíádì Máhánáímù,

81. Hésíbónì àti Jáṣérì lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.