orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì

1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.Réúbẹ́nì, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Ṣébúlúnì,

2. Dánì, Jóṣẹ́fù, Bẹ́ńjámínì; Náfítanì, Gádì: àti Áṣérì.

Júdà

Àwọn ọmọ Hésírónì

3. Àwọn ọmọ Júdà:Érì, Ónánì àti Ṣélà, àwọn mẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kénánì, ọmọbìnrin Súà Érì àkọ́bí Júdà, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.

4. Támárì, aya ọmọbìnrin Júdà, ó sì bí Fárésì àti Ṣérà sì ní ọmọ márùn ún ní àpapọ̀

5. Àwọn ọmọ Fárésì:Hésírónì àti Hámúlù.

6. Àwọn ọmọ Ṣérà:Ṣímírì, Étanì, Hémánì, Kálíkólì àti Darà, gbogbo wọn jẹ́ márùn ún.

7. Àwọn ọmọ Kárímì:Ákárì, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Ísírẹ́lì nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.

8. Àwọn ọmọ Étanì:Áṣáríyà

9. Àwọn ọmọ tí a bí fún Hésírónì ni:Jéráhímélì, Rámù àti Kélẹ́bù.

Láti ọ̀dọ̀ Rámù ọmọ Hésírónì

10. Rámù sì ni babaÁmínádábù, àti Ámínádábù baba Náṣónì olórí àwọn ènìyàn Júdà.

11. Náṣónì sì ni baba Sálímà, Sálímà ni baba Bóásì,

12. Bóásì baba Óbédì àti Óbédì baba Jésè.

13. Jésè sì ni BabaÉlíábù àkọ́bí Rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kẹjì sì ni Ábínádábù, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣíméà,

14. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Nàtaníẹ́lì, ẹlẹ́ẹ̀káàrùn-ún Rádáì,

15. ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Ósémù àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dáfídì.

16. Àwọn arábìnrin wọn ni Ṣérúà àti Ábígáílì. Àwọn ọmọ mẹ́ta Ṣérúà ni Ábíṣáì, Jóábù àti Ásáélì.

17. Ábígáílì ni ìyá Ámásà, ẹni tí baba Rẹ̀ sì jẹ́ Jétérì ará Íṣímáẹ́lì.

Kélẹ́bù ọmọ Hésírónì

18. Kélẹ́bù ọmọ Hésírónì ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó Rẹ̀ Ásúbà (láti ọ̀dọ̀ Jéríótù). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Rẹ̀: Jéṣérì, Ṣóbábù àti Árídónì.

19. Nígbà tí Ásúbà sì kú, Kélẹ́bù sì fẹ́ Éfúrátì ní aya, ẹni tí ó bí Húrì fún un.

20. Húrì ni baba Úrù, Úrù sì jẹ́ baba Bésálélì.

21. Nígbà tí ó yá, Hésírónì sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Mákírì baba Gílíádì (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Ṣégúbù.

22. Ṣégúbù sì jẹ́ bàbá Jáírì, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́talélógún ní ilẹ̀ Gílíádì.

23. (Ṣùgbọ́n Gésúrì àti Árámù sì fi agbára gba Hafoti Jáírì, àti Kénátì pẹ̀lú gbogbo agbégbé Rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì.

24. Lẹ́yìn tí Hésírónì sì kú ni Kélẹ́bù Éfúrátà, Ábíà ìyàwó Rẹ̀ ti Hésírónì sì bí Áṣúrì baba Tẹ́kóà fún un

Jéráhímélì ọmọ Hésírónì

25. Ọmọ Jéráhímélì àkọ́bí Hésírónì:Rámà ọmọ àkọ́bí Rẹ̀ Búnà, Órénì, óṣémù àti Áhíjà.

26. Jéráhímélì ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Átarà; ó sì jẹ́ ìyá fún Ónámù.

27. Àwọn ọmọ Rámà àkọ́bí Jéráhímélì:Másì, Jámínì àti Ékérì.

28. Àwọn ọmọ Ónámù:Ṣámáì àti Jádà.Àwọn ọmọ Ṣámáì:Nádábù àti Ábísúrì.

29. Orúkọ ìyàwó Ábísúrì ni Ábíháílì ẹni tí ó bí Áhíbánì àti Mólídì.

30. Àwọn ọmọ NádábùṢélédì àti Ápáímù. Ṣélédì sì kú láìsí ọmọ.

31. Àwọn ọmọ Ápáímù:Isì, ẹnití ó jẹ́ baba fún Ṣésánì.Ṣésánì sì jẹ́ baba fún Áhíláì.

32. Àwọn ọmọ Jádà, arákùnrin Ṣámáì:Jétérì àti Jónátanì. Jétérì sì kú láìní ọmọ.

33. Àwọn ọmọ Jónátanì:Pélétì àti Ṣásà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jéráhímẹ́lì.

34. Ṣésánì kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Éjíbítì tí orúkọ Rẹ̀ ń jẹ́ Járíhà.

35. Ṣẹ́sánì sì fi ọmọ obìnrin Rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ Rẹ̀ Járíhà, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ Rẹ̀ jẹ́ Átaì.

36. Átaì sì jẹ́ baba fún Nátanì,Nátanì sì jẹ́ baba fún Ṣábádì,

37. Ṣábádì ni baba Éfúlálì,Éfúlálì jẹ́ baba Óbédì,

38. Óbédì sì ni baba Jéhù,Jéhù ni baba Ásáríyà,

39. Ásáríyà sì ni baba Hélésì,Hélésì ni baba Éléáṣáì,

40. Éléáṣáì ni baba Ṣísámálì,Ṣísámálì ni baba Ṣálúmù,

41. Ṣálúmù sì ni baba Élísámà.

Ìdílé Kálẹ́bù

42. Àwọn ọmọ Kálébù arákùnrin Jérámélì:Méṣà àkọ́bí Rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣífì àti àwọn ọmọ Rẹ̀ Méréṣà, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hébúrónì.

43. Àwọn ọmọ Hébúrónì:Kórà, Tápúà, Rékémù, àti Ṣémà.

44. Ṣémà ni baba Ráhámú Ráhámù sì jẹ́ baba fún Jóríkéámù. Rékémù sì ni baba Ṣémáì.

45. Àwọn ọmọ Ṣémáì ni Máónì, Máónì sì ni baba Bétí-Ṣúri.

46. Éfà Obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Hárà nì, Mósà àti Gásésì, Háránì sì ni baba Gásésì.

47. Àwọn ọmọ Jádáì:Régémù, Jótamù, Gésánì, Pétélì, Éfà àti Ṣáfù.

48. Mákà obìnrin Kélẹ́bù sì ni ìyá Ṣébérì àti Tíránà.

49. Ó sì bí Ṣáfà baba Mákíbénà, Ṣéfà baba Mákíbénà àti baba Gíbéà: ọmọbìnrin Kélẹ́bù sì ni Ákíṣà.

50. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kélẹ́bù.Àwọn ọmọ Húrì, àkọ́bí Éfúrátà:Ṣóbálì baba Kiriati-Jéárímù.

51. Ṣálímà baba Bétíléhẹ́mù àti Háréfù baba Bẹti-Gádérì.

52. Àwọn ọmọ Ṣóbálì baba Kíríátì-Jéárímù ni:Háróè, ìdajì àwọn ará Mánáhítì.

53. Àti ìdílé Kíríátì-Jéárímù: àti àwọn ara Ítírì, àti àwọn ará Pútì, àti àwọn ará Ṣúmátì àti àwọn ará Mísíhí-ráì: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sórátì àti àwọn ará Ésítaólì ti wá.

54. Àwọn ọmọ Ṣálímà:Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àti àwọn ará Nétófátì, Atírótì Bẹti-Jóábù, ìdajì àwọn ará Mánátì, àti Ṣórì,

55. Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jábésì: àti àwọn ọmọ Tírátì àti àwọn ará Ṣíméátì àti àwọn ará Ṣúkátì. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Kénì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hámátì, baba ilé Kélẹ́bù.