orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ilé Àti Ìdílé Dáfídì

1. Nísinsìn yìí Hírámù àti ọba Tírè rán oníṣẹ́ sí Dáfídì, àti pẹ̀lú igi kédérì pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.

2. Dáfídì sì mọ Ísírẹ̀lì àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì àti pé Ìjọba Rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwon ènìyàn Rẹ̀.

3. Ní Jérúsálẹ́mù Dáfídì mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di bàbá àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.

4. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣámúyà, Ṣóbábù, Nátanì, Ṣólómónì,

5. Íbárì, Élíṣúà, Élífélétì,

6. Nógà, Néfégì, Jáfíà,

7. Élísámà, Bélíádà, àti Élífélétì.

Dáfídì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Fílístínì

8. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dáfídì ní ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dáfídì gbọ́ nípa Rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.

9. Nísinsìn yìí àwọn ará Fílístínì ti wá láti gbógun ti àfonífojì Réfáímù;

10. Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Fílístínì lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ̀n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”

11. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti àwọn ènìyàn Rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Pérásímù, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dáfídì lórí àwọn ọ̀ta mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Pérásímù.

12. Àwọn ará Fílístínì sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dáfídì sì paá láṣẹ láti jó wọn nínú iná.

13. Lẹ́ẹ̀kan síi àwọn ará Fílístínì gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì,

14. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì tún bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má se gòké tàrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi Múlíbérì.

15. Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró yíyan ẹsẹ̀ ní orí òkè igi Bálísámù, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fi hàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Fílístínì.

16. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọ lu àwọn ọmọ ogun Fílístínì láti gbogbo ọ̀nà Gíbíónì lọ sí Géṣérì.

17. Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dáfídì tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀ èdè bẹ̀rù Rẹ̀.