orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Pínpín Àwọn Àlùfáà.

1. Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Árónì:Àwọn ọmọ Árónì ni Nádábù, Ábíhù, Élíásérì àti Ítamárì.

2. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; Bẹ́ẹ̀ ni Élíásérì àti Ítamárì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

3. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.

4. A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.

5. Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.

6. Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.

7. Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù,èkejì sí Jédáià,

8. Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù,ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù,

9. Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà,ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì,

10. Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì,ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà,

11. Ẹkẹ́sàn sì ni Jésúà,ẹ̀kẹ́wà sì ni Ṣékáníà,

12. Ẹ̀kọ́kànlá sì ni Élíásíbù,ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jákímù,

13. Ẹ̀kẹtàlá sì ni Húpà,ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jéṣébéábù,

14. Ẹkẹdógun sì ni Bílígà,ẹ̀kẹ́rìndílogún sì ni Ímerì

15. Ẹ̀kẹtàdílógún sì ni Héṣírì,ekejìdílógún sì ni Háfísesì,

16. Ẹ̀kọkàndílógún sì ni Pétalà,ogún sì ni Jéhésékélì,

17. Ẹ̀kọ́kànlélógún sì ni Jákínì,ẹ̀kẹ́rìnlélogún sì ni Gámúlì,

18. Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Déláyà,ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Másíà.

19. Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí pàṣẹ fun wọn.

Ìyòókù Nínú Àwọn Ọmọ Léfì.

20. Ìyòókù àwọn ọmọ Léfì:láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámúríamù: Ṣúbáelì;láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣúbáélì; Jédeíà.

21. Àti gẹ́gẹ́ bí Réhábíà, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Réhábíà:Íṣíà sì ni alákọ́kọ́.

22. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Iṣárì: Ṣélómótì;láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣélomótì: Jáhátì.

23. Àwọn ọmọ Hebúrónì: Jéríyà alákọ́kọ́, Ámáríyà elẹ́kẹjì, Jáhásélì ẹlẹ́kẹta àti Jékáméámù ẹlẹ́kẹrin.

24. Àwọn ọmọ Húsíélì: Mikà;nínú àwọn ọmọ Míkà: Ṣámírù.

25. Àwọn arákùnrin Míkà: Íṣíà;nínú àwọn ọmọ Íṣíà: Ṣekaríyà.

26. Àwọn ọmọ Mérarì: Málì àti Múṣì.Àwọn ọmọ Jásíà: Bẹ́nò.

27. Àwọn ọmọ Mérárì:Lati Jasíà: Bẹ́nò, Ṣóhámù, Ṣákúrì àti Íbírì.

28. Láti Málì: Élíásérì, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.

29. Láti Kíṣì: Àwọn ọmọ Kíṣì:Jérámélì.

30. Àti àwọn ọmọ Muṣì: Málì, Édérì àti Jérímotì.Èyí ni àwọn ọmọ Léfì, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31. Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Árónì ṣe ṣẹ́, níwáju ọba Dáfídì àti Ṣádókì, Áhímélékì, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ìdilé àgbààgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arakùnrin wọn kéékèèkéé.