orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ìṣẹ́gun Dáfídì

1. Ní àkókò kan, Dáfídì kọlu àwọn ará Fílístínì, ó sì sẹ́gun wọn. Ó sì mú Gátì àti àwọn ìlétò agbègbè Rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Fílístínì.

2. Dáfídì borí àwọn ará Móábù, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

3. Ṣíbẹ̀, Dáfídì bá Hádádáṣérì ọba Ṣóbà jà, jìnnà láti fi ìdarí Rẹ̀ kalẹ̀ lẹ́bàá odò Éúfúrétè.

4. Dáfídì fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1000) kẹ̀kẹ́ Rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) a gun kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá méjì ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹsin náà.

5. Nígbá ti àwọn ará Áráméà nì ti Dámásíkù wá láti ran Hadadésérì ọba Ṣóbà lọ́wọ́, Dáfídì lu ẹgbàá méjì wọn bọ lẹ̀.

6. Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Áráméánì ti Dámásíkù, àwọn ará Áráméánì sì ń sìn ní abẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìsákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

7. Dáfídì mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadésérì gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jérúsálẹ́mù.

8. Láti Tébà àti Kúnì, ìlú tí ó jẹ́ ti Hádádéṣérì, Dáfídì mú ọ̀pọ̀ tánganran tí Ṣólómónì lò láti fi ṣe òkun tan-gan-ran, àwọn òpó àti orísìí ohun èlò tan-gan-ran.

9. Nígbà tí Tóù ọba Hámátì gbọ́ pé Dáfídì ti borí gbogbo ọmọ ogun Hádádéṣérì ọba Ṣóbà.

10. Ó rán ọmọ Rẹ̀ Ádórámì sí ọba Dáfídì láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun Rẹ̀ nínú ogun lórí Hádádéṣérì, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tóù. Ádórámì mú oríṣiríṣi ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti tan-gan-ran wá.

11. Ọba Dáfídì ya ohun èlò wọ̀n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí: Édómù àti Móábù, ará Ámónì àti àwọn ará Fílístínì àti Ámálékì.

12. Ábíṣáì ọmọ Ṣeruíà, lu méjìdínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Édómù bolẹ̀ ní àfonífojì iyọ̀.

13. Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì. Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

Àwọn Oníṣẹ́ Dáfídì.

14. Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16. Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé;

17. Bénáyà ọmọ Jéhóíádà jẹ́ olórí àwọn kérétì àti pélétì; àwọn ọmọ Dáfídì sì jẹ́ àwọn olóyè onísẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.