orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà Dáfídì wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ọrẹ síṣun fún Ísírẹ́lì.”

Ìmúrasílẹ̀ Fún Ilé Tí A Kọ́ Fún Ìsìn Ọlọ́run

2. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì paláṣẹ láti kó àwọn àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbé-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run.

3. Ó sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣọ́ fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n.

4. Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kédárì tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Ṣídónì àti àwọn ará Tírè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì wá fún Dáfídì.

5. Dáfídì wí pé, Ọmọ mi Sólómónì ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìríri, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.

6. Nígbà náà ó pe Sólómónì ọmọ Rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún-un Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7. Dáfídì sì wí fún Sólómónì pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi.

8. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.

9. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀.

10. Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba Rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdi ìtẹ́ ìjọba Rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì láéláé.’

11. “Nísinsìn yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.

12. Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ se aláṣẹ lórí Ísírẹ́lì, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́.

13. Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mósè fun Ísírẹ́lì ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.

14. “Èmi ti gba Ìpọ́nju ńlá láti ṣe fún ile Olúwa ọ̀kẹ́ márùn ún talẹ́ńtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà, Ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.

15. Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́.

16. Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin onísọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

17. Nígbà náà Dáfídì pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà ní Ísírẹ́lì láti ran Sólónmónì ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́.

18. Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìsẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn.

19. Nísinsìn yìí ẹ sí ọkàn yin payá àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”