orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kíróníkà 26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà.

1. Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà:Láti ọ̀dọ̀ Kórà: Méṣélémíò ọmọ Kórè, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Áṣáfì.

2. Méṣélémíà ní àwọn ọmọkùnrin:Ṣékáríáyà àkọ́bí,Jédíáélì ẹlẹ́ẹ̀kejì,Ṣébádíáyà ẹlẹ́ẹ̀kẹta,Játiníẹ́lì ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rin,

3. Élámù ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,Jehóhánánì ẹlẹ́ẹ̀kẹfààti Eliéhóémáì ẹlẹ́ẹ̀keje.

4. Obedi-Édómù ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú:Ṣémáíà àkọ́bí,Jéhóṣábádì ẹlẹ́ẹ̀kejì,Jóà ẹlẹ́ẹ̀kẹta,Ṣákárì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,Nétanélì ẹlẹ́ẹ̀kaàrún,

5. Ámíélì ẹ̀kẹfà,Ísákárì ẹ̀kejeàti péúlétaì ẹ̀kẹjọ(Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Óbédì Édómù).

6. Ọmọ Rẹ̀ Ṣémáíà ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé bàbá a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára.

7. Àwọn ọmọ Ṣémáíà: Ótínì, Refáélì, Óbédì àti Élíṣábádì; àwọn ìbátan Rẹ̀ Élíhù àti Sémákíà jẹ́ ọkùnrin alágbára

8. Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi Édómù; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Àtẹ̀lé Obedi Édómù méjìlélọ́gọ́ta (62) ni gbogbo Rẹ̀.

9. Móésélémíà ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún (18) ni gbogbo wọn.

10. Hósà ará Merà ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣímírì alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i se àkọ́bí, baba a Rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.

11. Hílíkíyà ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tábálíà ẹ̀kẹta àti Ṣékárià ẹ̀kẹrin, àwọn ọmọ àti ìbátan Hósà jẹ́ mẹ́talá (13) ni gbogbo Rẹ̀.

12. Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjísẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.

13. Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó.

14. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣélémíáyà, nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣekaríáyà, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

15. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà gúṣù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedì Édómù, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ Rẹ̀.

16. Kèké fún ẹnu ọ̀nà ìhà ìwọ̀ oòrùn àti Ṣálélà-etí ẹnu ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣúpímì àti Hósà.Olùsọ́ wà ní ẹ̀bá Olùsọ́:

17. Àwọn ará Léfì mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúṣù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.

18. Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnrarẹ̀.

19. Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ ti kórà àti Mérà.

Àwọn Afowópamọ́ àti Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìyòókù.

20. Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Léfì wọn wà ní ìdí ilé ìfowópamọ́ sí ti ile Ọlọ́run àti ilé ohun èlò yíyà sọ́tọ̀.

21. Àwọn ìran ọmọ Ládánì tí wọn jẹ́ ará Géríṣónì nípaṣẹ̀ Ládánì àti tí wọn jẹ́ àwọn olorí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Ládánì ará Gérísónì ni Jehíélì,

22. Àwọn ọmọ Jehíélì, Ṣétámì àti arákùnrin Rẹ̀ Jóélì. Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé Olúwa.

23. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámírámù, àwọn ará Íṣíhárì, àwọn ará Hébírónì àti àwọn ará Úṣíélì.

24. Ṣúbáélì, ìran ọmọ Gérísómì ọmọ Mósè jẹ́ oníṣẹ́ tí ó bojútó ilé ìṣúra

25. Àwọn ìbátan Rẹ̀ nípaṣẹ̀ Élíeṣérì: Réhábíà ọmọ Rẹ̀, Jéṣáíà ọmọ Rẹ̀, Jórámì ọmọ Rẹ̀.

26. Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tò nípa ọba Dáfídì, nípaṣẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákóso ọrọrún àti nipaṣẹ̀ alákóṣo ọmọ-ogun mìíràn.

27. Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé Olúwa ṣe.

28. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì aríranl àti nípasẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì ọmọ Nerì àti Joábù ọmọ Ṣeruíà gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀.

29. Láti ọ̀dọ̀ àwọn Iṣíhárì: Kénáníà àti àwọn ọmọ Rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn onísẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Ísirẹ́lì.

30. Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hébírónì: Háṣábíà àti àwọn ìbátan Rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀san (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Ísírẹ́lì, ìhà ìwọ̀ oòrùn Jórólánì fún gbogbo iṣẹ́ Olúwa àti fún iṣẹ́ ọba.

31. Níti àwọn ará Hébírónì, Jéríyà jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn ní ti ìdílé wọn. Ní ọdún kẹrin ìjọba Dáfídì, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrin àwọn ará Hébíronì ni a rí ní Jáṣérì ní Gílíádì.

32. Jéríyà ní ẹgbàáméjì, àti ọgọ́rin méje ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdilé ọba Dáfídì sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reúbẹ́nì àwọn ará Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Mánásè fun gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba.