orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jésù Wo Aláàrùn Ẹ̀gbà sàn

1. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jésù tún padà wọ Kápánámù, òkìkì kàn pé ó ti wà nínú ilé.

2. Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.

3. Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.

4. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù.

5. Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

6. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,

7. “È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? O ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”

8. Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

9. Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, ki o si máa rin?’

10. Ṣùgbọ́n ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Ènìyàn ní agbára ní ayé làti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ní.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé,

11. “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ẹní rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.”

12. Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé ẹní rẹ̀. Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”

Ìpè Léfì

13. Nígbà náà, Jésù tún jáde lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn.

14. Bí ó ti ń rin etí òkun lọ sókè, ó rí Léfì ọmọ Álíféù tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jésù sì wí fún un pé, “Tẹ̀ lé mi,” Léfì dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.

15. Ó si ṣe, bí ó sì ti jókòó tí oúnjẹ ni ilé Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí ti wọn pọ̀ ti wọn tẹ̀lé e.

16. Nígbà tí àwọn olùkọ òfin àti àwọn Farisí rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “È é ti rí tí ó fi ń bá àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

17. Nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá lati sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Lọ́wọ́ Jésù

18. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀?”

19. Jésù dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò se máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó sì wà lọ́dọ̀ wọn?

20. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.

21. “Kò si ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ túntún lẹ ògbólógbo ẹ̀wù, bí ó ba se bẹ́ẹ̀, èyí túntún ti a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fà ya kúrò lára ògbólógbòó, yíyọ́ rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.

22. Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì túntún sínú ìgò wáìni ògbólógbó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a si dàànu, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”

Olúwa Ọjọ́ Ìsinmi

23. Ó sì ṣe ni ọjọ ìsinmi, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrin oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọká.

24. Díẹ̀ nínú àwọn Farisí wí fún Jésù pé, “Wò ó, è é ṣe ti wọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”

25. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yín kò tí kà ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?

26. Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Ábíátarì olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ búrẹ́dì ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

27. Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ ìsinmi.

28. Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”