orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jésù Bọ́ Ẹgbàajì Ènìyàn

1. Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

2. Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàni wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ.

3. Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú-ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jínjìn wá.”

4. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí búrẹ́dì tí ó tó láti fibọ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”

5. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìsù búrẹ́dì mélòó lẹ ní lọ́wọ́?”Wọ́n fèsì pé, “isu búrédì méje.”

6. Nítori náà, ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi búrédì méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

7. Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jésù tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọ́n fún àwọn ènìyàn náà.

8. Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún.

9. Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ.

10. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jésù wọ inú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dálímánútà.

11. Àwọn Farisí tọ Jésù wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ̀n bèèrè fún àmì láti ọ̀run.

12. Jésù mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì? Lóòtọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín?”

13. Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apákejì òkun náà.

Yíìsìtì (Ohun tó ń mú búrẹ́dì wú) Farisí àti Hẹ́rọ́dù

14. Sùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú búrédì tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù búrédì kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn.

15. Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó ń mú búrẹ́dì wú àwọn Farisí àti ti Hẹ́rọ́dù.”

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrin ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú búrédì lọ́wọ́ ni?”

17. Jésù mọ ohun tí wọ́n sọ láàrin ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èése ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú búrẹ́dì lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsí i sì títí di ìsinyìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni?

18. Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹyín ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?

19. Nígbà ti mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣà jọ?”Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

20. “Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”

21. Ó sì wí fún wọn pé, “È é ha ti ṣe tí kò fi yé yin?”

Ìwòsàn Ọkùnrin Afọ́jú ní Bẹtisáídà

22. Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.

23. Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí?”

24. Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”

25. Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.

26. Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú.”

Pétérù Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Kírísítì Jẹ́

27. Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”

28. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”

29. Nígbà náà, Jésù bèèrè, “Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́?”Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà.”

30. Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.

Jésù Sọ Asọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú Ara Rẹ̀.

31. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le má sàì jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.

32. Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.

33. Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”

34. Nígbà náà ni Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó ṣe ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.

35. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là.

36. Nítorí èrè kí ni ó jẹ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù.?

37. Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàsípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?

38. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panságà àti ẹlẹ́sẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ-Ènìyàn yóò tijú rẹ nígbà tí o bá padà dé nínú ògo Baba rẹ, pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì mímọ́.”