orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Àmì Òpin Ayé

1. Bí Jésù ti ń jáde láti inú tẹ́ḿpìlì ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”

2. Jésù dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

3. Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,

4. “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpílì náà? Kí ni yóò sì jẹ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”

5. Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan yín.

6. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ni orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kírísítì,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́.

7. Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.

8. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jin ni ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.

9. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyè sára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú tẹ́ḿpìlì wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn gómìnà àti níwájú àwọn ọba pẹ̀lú, nítorí tí ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

10. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀ èdè kí òpin tó dé.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú yín, tí ẹ sì dúró níwájú adájọ́, ẹ má ṣe dààmú nípa ohun tí ẹ ó wí fún ààbò. Ẹ ṣáà sọ ohun tí Ọlọ́run bá fi sí yín lọ́kàn. Ẹ̀yin kọ́ ní yóò sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

12. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣekú pa òbí wọn.

13. Àwọn ènìyàn yóò kórira yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.

14. “Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró ní bí tí kò tọ́, tí a tí ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Jùdíà sá lọ sí orí òkè.

15. Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọkalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má si ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

16. Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà ṣẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀.

17. ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún fọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí.

18. Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé kí ìsákúrò nínú ewu yìí má ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù.

19. Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.

20. À fi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.

21. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kírísítì nìyìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.

22. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tàn àwọn ọmọ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

23. Nítorí náà, ẹ sọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!

24. “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,“ ‘òòrùn yóò sókùnkùn,òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

25. Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run.Ṣánmọ̀ àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ yóò wárìrì.’

26. “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ-Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọ̀sánmọ̀pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

27. Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ láti kó àwọn àyànfẹ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aye láti ìkángun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.

28. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kan lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ titun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fi hàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé.

29. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àwọn ohun abàmì wọ̀n-ọn-nì tí mo ti sọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tan, lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

30. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Iran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ

31. Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.

Ọjọ́ Àti Wákàtí Tí À Ko Mọ̀

32. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n. Ọlọ́run Baba nìkan ló mọ̀ ọ́n.

33. Ẹ máa sọra, Ẹ má ṣe sùn kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà ní ó àkókò ná yóò dé.

34. Ohun tí a lè fi bíbọ̀ mi wé ni ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò sí orílẹ̀ èdè mìíràn. Kí ó tó lọ, ó pín iṣẹ́ fún àwọn tí ó gbà ṣíṣẹ́, àní, iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe nígbà tí ó bá lọ, ó ní kí ọ̀kan nínú wọn dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà títí òun yóò fi dé.

35. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí sọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò da. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.

36. Pé nígbà tí bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun.

37. Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí ì fuń gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”