orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìnín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títi yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”

Ìparadà

2. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, Jésù mú Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù lọ sí orí òkè gíga ní apákan. Kò sí ẹlòmíràn pẹ̀lú wọn, ara rẹ̀ sì yípadà níwájú wọn.

3. Aṣọ rẹ̀ sì di dídán, ó sì funfun gbòò, tí alágbàfọ̀ kan láyé kò lè sọ di funfun bẹ́ẹ̀.

4. Nígbà náà ni Èlíjà àti Mósè farahàn fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jésù.

5. Pétérù sì wí fún Jesù pé, “Rábì, ó dára fún wa láti máa gbé níhìnín, si jẹ́ kí a pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fun ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.”

6. Nítorí òun kò mọ ohun tí òun ìba sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.

7. Ìkuukuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkúùkù náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”

8. Lójijì, wọ́n wo àyíká wọn, wọn kò sì rí ẹnìkan kan mọ́, bí kò ṣe Jésù nìkan ṣoṣo ni ó sì wà pẹ̀lú wọn.

9. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ-Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.

10. Nítorí náà, wọ́n pa nǹkan náà mọ́ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn ohun tí àjíǹde kúrò nínú òkú túmọ̀ sí.

11. Nísinsìnyìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, èéṣe tí àwọn olùkọ́-ófin ń sọ wí pé, “Èlíjà ní yóò kọ́kọ́ dé.”

12. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Èlíjà yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ-Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”

Ìwòsàn Ọmọkùnrin Ẹlẹ́mí Èṣù

14. Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹ̀ṣẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́-òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn.

15. Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.

16. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyàn-jiyàn?”

17. Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.

18. Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”

19. Ó sì dá wọn lóhun, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”

20. Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu.

21. Jésù béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”

22. Nígbàkúùgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná ati sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.

23. “Jéṣù sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó seé ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”

24. Lójúkan-náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”

25. Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”

26. Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàn tàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Héè, ọmọ náà ti kú.”

27. Ṣùgbọ́n Jésù fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó díde dúró.

28. Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè ní kọ́kọ́ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”

29. Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò se nípa àdúrà.”

30. Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Gálílì kọjá. Níbẹ̀ ni Jésù ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.

31. Nítorí o kọ̀ awọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, o si wí fun wọn pe, “A o fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ijọ́ kẹta.”

32. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.

Ta Ni Ó Ga Jùlọ?

33. Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”

34. Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn?

35. Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”

36. Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

37. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”

38. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”

39. Jésù sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.

40. Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa

41. Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kírísítì, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí.

Òkùnfà Ẹ̀sẹ̀

42. “Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun.

43. Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o gbé títí ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ọwọ́ kan ju kí a gbé ọ sínú iná àjóòkú ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì.

44. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nàá kì í kú

45. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnú, ó sàn kí ó di agẹ́sẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹṣẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì.

46. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nàá kì í sì í ku

47. Àti pé, bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sí inú iná ọ̀run àpáàdì.

48. Níbi ti“ ‘kòkòrò wọn kìí kú,,tí iná kì í sì í kú.’

49. Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò

50. “Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ agbára adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mu un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ni àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”