orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jésù Jẹ́jọ́ Níwájú Pílátù

1. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbààgbà, àwọn alùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jésù, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pílátù lọ́wọ́.

2. Pílátù sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”Jésù sì dáhùn pé, “Ìwọ wí.”

3. Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.

4. Pílátù sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”

5. Ṣùgbọ́n Jésù kò da lohùn síbẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pílátù.

6. Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àsà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún àwọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún.

7. Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bárábà. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n sọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn.

8. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pílátù, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.

9. Pílátù béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yín ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?”

10. òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jésù lé òun lọ́wọ́.

11. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Bárábà dá sílẹ̀ fún wọn.

12. Pílátù sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”

13. Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”

14. Nígbà náà ni Pílátù bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

15. Pilatù sì ń fẹ́ se èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jésù tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.

Àwọn Ọmọ-Ogun Fi Jésù Ṣe Ẹlẹ́yà

16. Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú gbangba (tí a ń pè ní Piretorioni), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun jọ.

17. Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.

18. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù

19. Wọ́n sì fi ọ̀pá ìyè lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ síi lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.

20. Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.

Wọ́n Kan Jésù Mọ́ Àgbélébùú

21. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Símónì ni orúkọ rẹ̀. Ará Kírénì ni. Òun ni baba Alekisáńdérù àti Rúfọ́ọ̀sì. Wọ́n sì mú un nípá, pé kí ó rú àgbélébùú Jésù.

22. Wọ́n sì mú Jésù wá sí Gọ́lgọ́tà, (èyí tí ìtúmọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí)

23. Wọ́n sì fi wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.

24. Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn báà lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.

25. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.

26. Àkọlé Ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

27. Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀.

28. Eléyìí mú àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.”

29. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Áà! Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì tí yóò sì tún un kọ́ láàrin ọjọ́ mẹ́ta.

30. Tí ó bá lágbára tó bẹ́ẹ̀, gba ara rẹ là, kí o sì ti orí àgbélébùú sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú.”

31. Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í sẹ̀sín láàrin ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà.

32. Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

Ikú Jésù

33. Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án.

34. Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ?” ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35. Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”

36. Nígbà náà ni ẹnìkan wá sáré lọ ki kàn-ìn-kàn-ìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jésù kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Èlíjà yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀.”

37. Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.

38. Aṣọ ìkélé tẹ́ḿpìlì sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.

39. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jésù rí i tí kígbe sókè báyìí tí ó sì èémí ìgbẹ̀yìn, ó wí pé, “Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í se.”

40. Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè. Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè.

41. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Gálílì máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìranṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerúsálémù.

Ìsìnkú Jésù

42. Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí se, ọjọ́ tó sáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú,

43. Jóṣẹ́fù ará Arimatíyà wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pílátù láti tọrọ òkú Jésù.

44. Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú. Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́.

45. Nígbà tí balógun-ọ̀rún náà sì fún Pílátù ni ìdánilójú pé Jésù ti kú, Pílátù yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jóṣẹ́fù.

46. Jóṣẹ́fù sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jésù kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.

47. Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè ń wò ó bi Jóṣẹ́fù ti n tẹ́ Jésù sí ibojì.