orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ọ̀rọ̀ Sítéfánù Sí Àwọn Àjọ Ìgbìmọ̀

1. Nígbà náà ni olorí àlùfáà wí pé, “Òtítọ́ ha ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́ fi kàn ọ́ bí?”

2. Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arakùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Ábúráhámù baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamíà, kí ó to ṣe àtìpó ni Háránì.

3. Ọlọ́run fún un pé, ‘Jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí ó sì lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.’

4. “Nígbà náà ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ṣe àtipó ni Háránì. Lẹ́yìn ìgbà tí baba rẹ̀ sì kú, Ọlọ́run mú un sípò padà wá sí ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀yin ń gbé báyìí.

5. Kò sí fún un ni ìní kan, àní tó bi ìwọ̀n ààyè ẹṣẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run se ìlérí fún pé, òun yóò fi ilẹ̀-ìní náà fún un àti fún àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí kò tí ì ní ọmọ.

6. Ọlọ́run sì sọ báyìí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ̀ yóò ṣe àtìpó ni ilẹ̀ àjèjì; wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú ni irínwó ọdún.’

7. Ọlọ́run wí pé, ‘Orílẹ̀-èdè náà tí wọn ó ṣe ẹrú fún ni èmi ó dá lẹ́jọ́; lẹ́yìn náà ni wọn ó sì wá sìn mí níhín yìí.’

8. Ó sì fún Ábúráhámù ni májẹ̀mú ìkọlà. Ábúráhámù bí Ísáákì, ó kọ ọ́ ní ilà-abẹ́ ni ijọ́ kẹjọ tí ó bí i. Ísáákì sí bí Jákọ́bù, Jákọ́bù sì bí àwọn baba ńlá méjìlá.

9. “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Jósẹ́fù, wọ́n sì tà á sí Íjíbítì; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,

10. ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Jósẹ́fù ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Fáráò ọba Íjíbítì; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.

11. “Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì àti ni Kénánì, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ.

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ pé Àlìkámà ń bẹ ni Íjíbítì, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní.

13. Nígbà kejì Jósẹ́fù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Fáráò.

14. Lẹ́yìn èyí, Jósẹ́fù ránsẹ́ pe Jákọ́bù baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ̀dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrúndínlọ́gọ́rin ènìyàn.

15. Nígbà náà ni Jákọ́bù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí.

16. A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣékémù, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Ábúráhámù rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Ámórì ní Sékémù ní iye-owó wúrà kan.

17. “Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Ábúráhámù sẹ kù dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbérù si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Íjíbítì.

18. Ṣùgbọ́n ọba mị̀íràn, ẹni tí kò mọ ohunkóhun nípa Jósẹ́fù, di alásẹ lórí ilẹ̀ Íjíbítì.

19. Òun náà ni ó ṣe àrékekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ-ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.

20. “Ní àkókò náà ni a bí Mósè, ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀.

21. Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.

22. A sì kọ́ Mósè ni gbogbo ọgbọ́n ara Íjíbítì, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.

23. “Nígbà tí Mósè di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Isríẹ́lì ará rẹ̀ wò.

24. Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ara Éjíbítì kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbéjà rẹ̀, ó gbẹ̀sàn ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ara Íjíbítì náà pa:

25. Mósè rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.

26. Ní ọjọ́ kejì Mósè yọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun ì bá sí parí rẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; è é ṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’

27. “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ tì Mósè sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ jẹ olórí àti onídàjọ́ wa?

28. Àbí ìwọ ń fẹ́ pa mi gẹ́gẹ́ bí o ti pa ará Íjíbítì lánàá?’

29. Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.

30. “Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Mósè ní ijù, ní òkè Sínáì, nínú ọ̀wọ́ iná ìgbẹ́.

31. Nígbà tí Mósè sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i,

32. Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù,’ Mósè sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dàṣà láti wò ó mọ́.

33. “Olúwa sì wí fún un pé, ‘Tú bátà rẹ kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ, nitorí ibi tí ìwọ gbé dúró sí yìí ilẹ̀ mímọ́ ni.

34. Ní rírí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsìn yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì.’

35. “Mósè náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ ańgẹ́lì, tí ó farahàn án ní ìgbẹ́, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè.

36. Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Íjíbítì, àti ni òkun pupa, àti ni ihà ní ogójì ọdún.

37. “Èyí ni Mósè náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’

38. Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú ańgẹ́lì náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sínáì, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.

39. “Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì;

40. Wọ́n wí fún Árónì pé ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ ọ̀nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mósè yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’

41. Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rúbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn se.

42. Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:“ ‘Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún miní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

43. Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gba ojúbọ Mólókù,àti ìràwọ̀ Ráfánì òrìṣà yín,àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ.Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Bábílónì.’

44. “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijú. Èyí tí a se gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mósè sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí ó ti rí.

45. Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì.

46. Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.

47. Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un,

48. “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

49. “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?ni Olúwa wí.Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi?

50. Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’

51. “Ẹ̀yin ọlọ́rùn-líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yín rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!

52. Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa.

53. Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn ańgẹ́lì ti fi fún ni, tí ẹ kò sí pa á mọ́.”

A Sọ Sítéfánù Ní òkúta Pa

54. Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payín keke sí i.

55. Ṣùgbọ́n Sítéfánù, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jésù dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

56. Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

57. Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú,

58. wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù.

59. Bí wọ́n ti ń sọ ọ́ ní òkúta, Sítéfánù gbàdúrà wí pé, “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mi mi.”

60. Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.