orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìpèlẹ́jọ Níwájú Fẹ́líkísì

1. Lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún Ananíyà olórí àlúfáà náà sọkalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti ẹnìkan, Tátúlù agbẹjọ́rò, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù fún baálẹ̀.

2. Nígbà tí a sí tí pè Pọ́ọ̀lù jáde, Tátúlù gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Fẹ́líkísì ó wí pé: “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ lá ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsù rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí.

3. Ní ibi gbogbo àti ní ọ̀nà gbogbo, Fẹ́líkísì ọlọ́lá jùlọ, ní àwa ń tẹ́wọ́gbà á pẹ̀lú ọpẹ́ gbogbo.

4. Ṣùgbọ́n kí èmi má baa dá ọ dúró pẹ́ títí, mo bẹ̀ ọ́ kí o fi ìyọ́nú rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ díẹ̀ lẹ́nu wa.

5. “Nítorí àwa rí ọkùnrin yìí, ó jẹ́ oníjàngbàn ènìyàn, ẹni tí ó ń dá rúkèrúdò ṣílẹ̀ láàrin gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo ayé. Òun ni aṣáájú búburú kan nínú ẹ̀yà àwọn Násárénè:

6. Ẹni tí ó gbìyànjú láti ba tẹ́ḿpílì jẹ́: ṣùgbọ́n àwa gbá a mú àwa sí fẹ báa ṣe ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin wa.

7. Ṣùgbọ́n Lísíà olórí ogun dé, ó fì agbára ńlá gbà á lọ́wọ́ wa:

8. Nígbà tí ìwọ fúnrarẹ bá wádìí ọ̀rọ̀ fínní fínni lẹ́nu rẹ̀, ìwọ ó lè ní òye òtítọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí àwa fi ẹ̀ṣùn rẹ̀ kàn án.”

9. Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.

10. Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀ tayọ̀ wí tí ẹnu mi.

11. Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerúsálémù láti lọ jọ́sìn.

12. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú:

13. Bẹ́ẹ̀ ní wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsìn yìí.

14. Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀le ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa-ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

15. mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkaráwọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtọ́, àti tí aláìsòótọ́.

16. Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí-ọkàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.

17. “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdun púpọ̀, mo wá sí Jerúsálẹ́mù láti mu ẹ̀bún wá fún àwọn ẹ̀nìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀.

18. Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú iyẹ̀wù tẹ́ḿpílì, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ́nú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárin àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo.

19. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Éṣíà wà níbẹ̀, àwọn tí ì bá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkohun sí mi.

20. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tíkarawọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀.

21. Bí kò ṣe tí gbolóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ ṣíta nígbà tí mo dúró láàrin wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín lóni yìí!’ ”

22. Nígbà tí Fẹ́líkísì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí òye sà yè e ní àyétan nípa ọ̀nà náà; ó tú wọn ká ná, ó ní, “Nígbà tí Lísíà olórí ogun bá ṣọ̀kalẹ̀ wá, èmi ó wádìí ọ̀ràn yín dájú.”

23. Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó fi Pọ́ọ̀lù sí a bẹ́ ìsọ́, ṣùgbọ́n kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.

24. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Fẹ́líkísì pẹ̀lú Dírúsílà ìyàwó rẹ̀ dé, obìrin tí í ṣe Júù. Ó ranṣẹ́ pé Pọ́ọ̀lù, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

25. Bí Pọ́ọ̀lù sì tí ń sọ àsọyé nípa tí òdodo àti àìrékọjá àti ìdájọ́ tí ń bọ̀, ẹ̀rù ba Fẹ́líkísì, ó dáhùn wí pé, “Èyí tí o sọ nì tó ná! Máa lọ nísinsìn yìí ná. Nígbà tí mo bá sì ní àkókò tí ó wọ̀, èmi ó ránṣẹ́ pè ọ́.”

26. Ní àkókó yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Pọ́ọ̀lù yóò mú owó-ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun baà lè dá a sílẹ̀: nítorí náà, a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkúgbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.

27. Lẹ́yìn ọdun méjì, Póríkíúsì Fẹ́sítúsì rọ́pò Fẹ́líkísì: Fẹ́líkísì ṣí ń fẹ́ se ojú rere fún àwọn Júù, ó fí Pọ́ọ̀lù sìlẹ́ nínú túbú.