orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fí di òní yìí.”

2. Nígbà yìí ni Ananíyà olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Pọ́ọ̀lù pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.

3. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ogiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan-an alára rú òfin nípa pípaṣẹ pé kí a lù mí!”

4. Àwọn tí ó dúró tì Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”

5. Pọ́ọ̀lù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù sàkíyèsí pé, apákan wọn jẹ́ Sádúsì, apákan sì jẹ́ Farisí, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisí, ọmọ Farisí sì ni èmi: mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

7. Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrin àwọn Farisí àti àwọn Sádúsì: àjọ sì pín sì méjì.

8. Nítorí tí àwọn Sádúsì wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí ańgẹ́lì, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisí jẹ́wọ́ méjèèjì:

9. Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisí dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí áńgẹ́lì kan tàbí ẹ̀mí kan ń baà sọ̀rọ̀?”

10. Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Pọ́ọ̀lù má baà di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrin wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

11. Ní òru ijọ́ náà Olúwa dúró tì Pọ́ọ̀lù, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerúsálémù, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Róòmù pẹ̀lú.”

Ìdìtẹ̀ Láti Pa Pọ́ọ̀lù

12. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, awọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Pọ́ọ̀lù:

13. Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ.

14. Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Pọ́ọ̀lù.

15. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí-ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”

16. Nígbà tí ọmọ arabínrin Pọ́ọ̀lù sí gbúrò ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù.

17. Pọ́ọ̀lù sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí-ogun lọ: nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”

18. Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí-ogun.Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Pọ́ọ̀lù òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sí bẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”

19. Olórí-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”

20. Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ sọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbimọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ bèèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.

21. Nítorí náà má ṣe gbọ́ ti wọn: nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsìn yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”

22. Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fí nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”

A gbé Pọ́ọ̀lù lọ Késáríà

23. Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ ṣí Kesaríà, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹ́ta òru.

24. Ó sì wí pé, kí wọn pèṣè ẹranko, kí wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Fẹ́líkísì baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

25. Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26. Kíláúdíù Lísíà,Sí Fẹ́líkísì baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:Àlàáfíà.

27. Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á: nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni í ṣe.

28. Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn.

29. Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fisùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n.

30. Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.

31. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gba Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì mú un lóru lọ si Áńtírípátírì, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn.

32. Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

33. Nígbà tí wọ́n dé Kesaríà, tí wọ́n sí fi ìwé fún baalẹ́, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú wá ṣíwájú rẹ̀.

34. Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó bèèrè pé agbégbé ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kílíkíà ni;

35. Ó ní, “Èmi yóò gbọ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfiṣùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì paṣẹ pé kí wọn pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní abẹ́ àmójútó àwọn olùsọ́ ní gbọ̀ngán-ídájọ́ ààfin Hẹ́rọ́dù.