orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sọ́ọ̀lù sì wà níbẹ̀, ó sì ní ohùn sí ikú rẹ̀.Ní àkókò náà, inúnibini ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerúsálémù, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Jùdíà àti Samaríà, àyàfi àwọn àpósítélì.

Wọ́n Ṣe Inúnibínu Sí Ìjọ, Wọ́n Sì Túkà

2. Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rè sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.

Fílípì Ní Samaríà

4. Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo, wọn ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.

5. Fílípì sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaríà, ó ń wàásù Kírísítì fún wọn.

6. Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ̀, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Fílípì ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkan kan fíyèsí ohun tí ó ń sọ.

7. Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúkùn-ún ni ó sì gba ìmúláradá.

8. Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.

Símónì Onídán

9. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Símónì, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaríà. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.

10. Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ Ńlá.”

11. Wọ́n bọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jésù Kírísítì, a bámítíìsì wọn.

13. Símónì tikararẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bámitíìsì rẹ̀, ó sì tẹ̀ṣíwájú pẹ̀lú Fílípì, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Fílípì ṣe, ẹnu sì yà á.

14. Nígbà tí àwọn àpósítélì tí ó wà ní Jerúsálémù sí gbọ́ pé àwọn ara Samaríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù Àti Jòhánù sí wọn.

15. Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́:

16. nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bá lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitíìsì wọn lórúkọ Jésù Olúwa ni.

17. Nígbà náà ni Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

18. Nígbà tí Símónì rí i pé nípa gbígbe ọwọ́ leni ni a ń ti ọwọ́ àwọn àpósítélì fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,

19. ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20. Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

21. Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déedé níwájú Ọlọ́run.

22. Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búrurú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dári ète ọkàn rẹ jì ọ́.

23. Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹrò ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”

24. Nígbà náà ni Símónì dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

25. Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Pétérù àti Jòhánù padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì wàásù ìyìn rere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn Samaríà.

Fílípì Àti Ìwẹ̀fà Ìtíópíà

26. Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà.”

27. Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsí, ọkùnrin kan ará Etiópíà, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọdọ̀ Káńdákè ọba-bìnrin àwọn ara Etiópíà, ẹni tí í se olórí ìsúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerúsálémù láti jọ́sìn,

28. Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà.

29. Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”

30. Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”

31. Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.

32. Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.

33. Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́-ododo dùn ún:Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀?Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”

34. Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Fílípì pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmìíràn?”

35. Fílípì sí ya ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé-mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìn rere ti Jésù fún un.

36. Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitíìsì?”

37. Fílípì sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitíìsì rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jésù Kírísítì Ọmọ Ọlọ́run ni.”

38. Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Fílípì àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Fílípì sì bamitíìsì rẹ̀.

39. Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Fílípì lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.

40. Fílípì sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Ásótù, bí ó ti ń kọ́ja lọ, o wàásù ìyìn rere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesaríà.