orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ní Ìkóníónì

1. Ó sí ṣe, ni Ìkóníónì, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà júmọ́ wọ inú sínágọ́gù àwọn Júù lọ, wọ́n sì sọ̀rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláìkọlà gbàgbọ́,

2. Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbàgbọ́ Júù rú ọkàn àwọn aláìkọlà sókè, wọ́n sì mú wọn ni ọkàn ìkorò sí àwọn arákùnrin náà.

3. Nítorí náà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà gbé ibẹ̀ pẹ́, wọ́n ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú Olúwa, ẹni tí ó jẹ̀rìí sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, ó sì yọ̀ǹda kí iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu máa ti ọwọ́ wọn ṣe.

4. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà pín sí méjì: apákan dàpọ̀ mọ́ àwọn Júù, apákan pẹ̀lú àwọn àpósítélì.

5. Bí àwọn aláìkọlà, àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olórí wọn ti fẹ́ kọlù wọ́n láti fi àbùkù kàn wọ́n, àti láti sọ wọ́n ní òkúta,

6. wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sálọ sí Lísírà, àti Dábè, àwọn ìlú Líkáóníà àti sí agbégbé àyíká.

7. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ń wàásù ìyìn rere.

Ní Lísírà àti Dábì

8. Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lísírà, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí.

9. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá.

10. Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánsán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.

11. Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Líkáóníà, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!”

12. Wọn sì pe Bánábà ni Ṣeusi àti Pọ́ọ̀lù ni Hamisi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ síṣọ.

13. Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí.

14. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àpósítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé:

15. “Ará, è é ṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìn rere fún yín, kí ẹ̀yin baà lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

16. Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà ti wọn.

17. Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”

18. Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rúbọ bọ wọ́n.

19. Àwọn Júù kan sì ti Áńtíókù àti Ìkóníónì wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kan padà, wọ́n sì sọ Pọ́ọ̀lù ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣèbí ó kú.

20. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Bánábà lọ sí Dábè.

Ìpadàbọ̀ Sí Áńtíokù Ti Síríà

21. Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìn rere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lísírà, àti Ikóníónì, àti Áńtíókù,

22. wọn sì ń mú àwọn ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró ní ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ̀njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.

23. Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi à wọ́n lé ẹni gbàgbọ́ Olúwa lọ́wọ́.

24. Nígbà tí wọn sí la Pásídíà já, wọ́n wá sí Páḿfílíà.

25. Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Págà, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ataláyà:

26. Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Ańtíókù ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí

27. Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà.

28. Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.