orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Tìmótíù Darapọ̀ Mọ́ Pọ́ọ̀lù Àti Sílà

1. Ó sì wá sí Dábè àti Lísírà: sí kíyèṣi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Tìmótíù, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Gíríkì ní baba rẹ̀.

2. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lísírà àti Ìkóníónì.

3. Òun ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbégbé wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Gíríkì ni baba rẹ̀.

4. Bí wọn sì ti ń la àwọn Ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn àpósítélì àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerúsálémù, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́.

5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹmúlẹ̀ ní ìgbágbọ́, wọn ṣí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojumọ́.

Ìran Pọ́ọ̀lù Nípa Arakùnrin Makedóníà

6. Wọ́n sì la agbégbé Fírígíà já, àti Gálátíà, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti ṣọ ọ̀rọ̀ náà ni Éṣíà.

7. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Mísíà, wọ́n gbìyànjú láti lọ ṣí Bítíníà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jéṣù kò gbà fún wọn.

8. Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì.

9. Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, “Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”

10. Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn.

Ìyípadà Lìdíà Ní Fílípì

11. Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì;

12. Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí (àwọn ara Róòmù) tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán.

13. Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókóò, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ ṣọ̀rọ̀.

14. Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lìdíà, tí ó ń ta àwọn aró ẹlẹ́ṣè àlùkò, gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísì ohun tí a tí ẹnu Pọ́ọ̀lù sọ.

15. Nígbà tí a sí bamitíìsì rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.

16. Bí àwa tí nlọ ṣí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí ìwosẹ́, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀:

17. Òun náà ni ó ń tọ Pọ́ọ̀lù àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!”

18. Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Pọ́ọ̀lù bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jéṣù Kíríṣítì kí o jáde kúrò lára rẹ̀!” Ó sí jáde ni wákàtí kan náà.

19. Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì ríì pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ;

20. Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ;

21. Wọ́n sí n kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.”

22. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì wọn: àwọn olórí sí fà wọ́n láṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fí ọ̀gọ̀ lù wọ́n.

23. Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára:

24. Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n ṣínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́ṣẹ̀.

25. Ṣùgbọ̀n láàrin ọ̀gànjọ́ Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.

26. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpilẹ̀ ile túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ilẹ̀kùn sì sí, ìde gbogbo wọn sì tú ṣílẹ̀.

27. Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí sí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ara túbú ti sá lọ.

28. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má se pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn yìí!”

29. Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà.

30. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”

31. Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”

32. Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.

33. Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.

34. Ó sì mú wọn wá ṣí ilé rẹ̀, ó sì gbé ounjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.

35. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà ṣílẹ̀.”

36. Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Pọ́ọ̀lù, wí pé, “Àwọn onídájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da yín ṣílẹ̀: ǹjẹ́ nisinsìnyìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”

37. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bí, àwa ẹni tí ì ṣe ara Róòmù: ṣe nísinsìnyìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde nikọ̀kọ̀? Àgbẹdọ̀! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkara wọn wá mú wa jáde!”

38. Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàjọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù ni wọ́n.

39. Wọ́n sì wá, wọ́n sìpẹ̀ fún wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà.

40. Wọ́n sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lídíà lọ: nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.