Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.